Ǹjẹ́ o mọ̀ pé o lè ta epo bẹntiróòlù fúnra rẹ láì nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nílé epo? Ohun tí o ni láti ṣe rèé

Ọkunrin kan n ra epo funra rẹ nile epo NNPC

Oríṣun àwòrán, NNPC/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igba ọtun ti de o, awọn awakọ ti lanfaani bayii lati ra epo funra wọn nile epo lai nilo iranlọwọ ẹnikẹni pẹlu eto ti ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPCL ṣe agbekalẹ.

Eto ti NNPC ṣẹṣẹ gbe kalẹ yii ti fawọn onibaara lanfaani lati ra epo sinu ọkọ tabi jẹrika funra wọn lai nilo iranwọ ẹnikẹni nile epo.

Aapu alagbeka lawọn onibaara yoo maa lo lati sanwo fun epo ti wọn ba fẹ ra.

Eyi yoo fopin si sisan owo fawọn to maa n ta epo fawọn onimọto nile epo tẹlẹ.

Ileeṣẹ NNPC ṣalaye ninu atẹjade kan to fi lede loju opo X rẹ wi pe awọn n gbero lati jẹ kawọn onibaara awọn lanfaani lati maa ra epo funra wọn nile epo bii aadọta si aadọrin kaakiri orilẹede Naijiria laarin ọṣu mẹfa si asiko yii.

Yatọ si bawọn alagbata epo ṣe n maa n ta epo fawọn onimọto atawọn to ba fẹ ra epo tẹlẹ, ilana tuntun yii ti fawọn onibaara lanfaani lati sọ iye epo ti wọn fẹ ra, o si tun fun wọn lanfaani lati sanwo epo ti wọn fẹ ra lori aapu.

Nọmba ti wọn n pe ni ''code'' ti wọn yoo ri lori aapu ni wọn yoo maa fi ra epo ti wọn ba fẹ ra nile epo.

NNPC ti wa ṣalaye bawọn onibaara ṣe le ra epo funra wọn lawọn ile epo NNPC lai nilo ẹnikẹni nile epo.

Wo bi o ṣe le ra epo funra rẹ lai nilo iranwọ ẹnikẹni nile epo NNPC:

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbesẹ akọkọ tawọn onimọto to ba fẹ maa ra epo funra wọn ni lati gbe ni lati ni aapu NRL lori foonu wọn, loju opo X NNPC naa ni wọn yoo to ri aapu yii.

Igbesẹ keji ni pe wọn o ṣi aapu yii, nibẹ ni wọn yoo sọ pe awọn fẹ ra epo ti wọn yoo si tun sọ iru epo ti wọn fẹ ra.

Igbesẹ kẹta ni lati wo ile epo NNPC ti o ti le ra epo funra rẹ.

Eyi ṣe pataki tori gbogbo ile epo NNPC kọ ni eeyan ti le ra epo funra rẹ lai nilo iranlọwọ ẹnikẹni.

Lẹyin ti o ba ti mọ ile epo to ti le ra epo funra rẹ tan ni wa a tẹ iye epo ti o fẹ ra sori aapu naa.

Ti o ba ti sanwo tan ni aapu NRL yoo gbe risiiti jade, bakan naa ni aapu yii yoo fun ọ ni ''code'' ti wa fi ra epo.

Ti o ba ti de ile epo, tẹ nọmba mẹjọ to wa nibi ''code'' ti o ri lori aapu NRL ki o si tẹ bọtini '#'.

Lẹyin naa ni wa a gbe ọpa ti wọn fi n ta epo ti wa si ra epo iye owo ti o san.

Ẹwẹ, igbakeji aarẹ ẹka epo rọbi wiwa nileeṣẹ NNPC, Mumuni Dagazu, sọ pe ilana tuntun tita epo yii wa lara igbesẹ t ileeṣẹ naa n gbe lati mu okowo ohun amuṣagbara gbooro sii.

Shettima Baba-Kukawa to jẹ igbakeji ọga agba ẹka to n ri si epo tita ni NNPC sọ pe awọn onibaara le ti sanwo epo ti wọn fẹ ra lori foonu ki wọn to de ile epo ti wọn ti ra epo.

NNPC tun sọ pe awọn onibaara tun le lo ilana tuntun yii lati ra afẹfẹ gaasi, bakan naa tun ni wọn sọ pe awọn ti ọkọ wọn ba n lo ina ẹlẹtiriki naa le lo awọn ile epo yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post