BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
APC àti PDP pe ẹjọ́ tako èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tó gbé Adeleke wọlé fún sáà kejì
Ọjọ mọkanlelogun lẹyin eto idibo ni awọn ẹgbẹ oṣelu ti esi ibo naa ko ba tẹ lọrun ni lati gba ile ẹjọ lọ lati pe esi ibo naa nija.
Ṣé lóòótọ́ ni Tinubu buwọ́lù ẹ̀wọ̀n gbére fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá kùnà láti dá owóòyá NELFUND padà fún ìjọba? Àlàyé rèé
Lọdun 2024 ni Tinubu buwọlu ofin idasilẹ ajọ NELFUND to n ri si eto owooya fawọn akẹkọọ ti ko rọwọ họri lawọn ile ẹkọ giga ni Naijiria.
Sẹ́nétọ̀ Buba sọ̀rọ̀ lórí fídíò tó gba orí ayélujára pé ó ṣàtìlẹyìn fáwọn agbébọn
Ninu fidio naa ni Hassan ti fẹsun kan pe niṣe ni Sẹnetọ naa n idanilẹkọọ fawọn agbebọn to pe orukọ wọn ni Babangida ati Lema.
Bàlúù yà wọ ojú pópó, kọlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ́, ẹ̀mí márùn ún lọ síi, ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lọ́gán
Pupọ awọn to farapa naa lo jẹ pe wọn ha mọ inu tabi abẹ ọkọ ni to si jẹ pe awọn panapana ni lati sa ipa kikankikan ki wọn to le yọ wọn.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 1,00
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Fídíò, Àwọn kan fẹ́ kí n sọ ₦25 milíọ̀nù tí Ogogo tọ́jú sọ́wọ́ mi di owó Mọ́ṣáláṣí ṣùgbọ́n mo ní rárá – Ìmáàmù ìlú Ilaro, Duration 5,02
Imaamu Adewumi ni lẹyin abẹwo ti oun ṣe gbẹyin si Ogogo nigba to wa ni ileewosan to n gba itọju lo san owo naa si aṣuwọn oun.
Mo fẹ lọ fún ìsinmi díẹ̀ kí ara lè tù mí láti lé sin àwọn èèyàn Osun dáadáa - Gómìnà Adeleke
Irinajo isinmi naa n waye lẹyin ọsẹ mẹta ti Adeleke bori eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ọṣun.
Kí ló ṣokùnfà ikú ọmọ ìyá mẹ́ta lọ́jọ́ kan náà l'Ondo? Ohun tí a mọ̀ rèé
Ẹkun sọ lẹyin ti wọn ri oku awọn mẹtẹẹta ninu odo kekere kan, lẹyin ti wọn ti n wa wọn kiri.
Ẹ yàgò fún òṣèlú kí epo má baà ta sí àlà yín, Makinde kìlọ̀ fún àwọn Ọba Oyo
Gomina naa tun ke si awọn ori ade ki wọn tẹsiwaju lati maa gbe ni alaafia pẹlu awọn ti wọn jẹ ọba le lori.
Wo àwọn alága EFCC tẹ́lẹ̀rí tí wọ́n ti fẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ kàn
Alaga ajọ EFCC tẹlẹri, Abdulrasheed Bawa, dero atimọle ajọ ọtẹmulẹyẹ DSS lọdun 2023 lori ẹsun ṣiṣe ṣowo ilu kumọ kumọ, ṣiṣi ipo lo ati didari owo dukia ijọba ti EFCC ta si ibomiran.
'Mo wá sí Naijiria láti kojú ọmọ Yahoo tó fẹ́ lu ìyá mi ni jìbìtì àmọ́ ohun tí mo bábọ̀ rèé'
Nọmba idanimọ ori foonu rẹ ṣafihan pe Naijiria lo ti n fi awọn atẹjiṣẹ ranṣẹ sori foonu iya Carlos lodi si Syria to ni oun wa gẹgẹ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika to ni oun jẹ.
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn èèyàn kan wà tí wọn kò ní ilà ọwọ́? Ohun tó fà á ree
Aini ila ọwọ tabi tẹsẹ ti oloyinbo n pe ni adermatoglyphia jẹ nnkan ti wọn maa n bi mọ eeyan, amọ, iru rẹ ko wọpọ rara.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fídíò, Ìfẹ́ tí Ajá mi fi hàn sí mi, ló gba ẹ̀mí mi là lásìkò tí mo fẹ́ pa ara mi - Oreoluwa Osoba, Duration 2,20
BBC bá Oreoluwa Osoba sọ̀rọ̀ láti mọ ohun tó fa ìrònú sí i lára, tó ṣe fẹ́ pa ara rẹ̀ àti ipa tí Ajá tó ń sìn nínú ilé kó láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
Kí ló fa ikú pásítọ̀ ìjọ Celestial kan àti ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jà tán? Àlàyé rèé
"Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ, lati mọ kulẹkulẹ bi ọrọ naa ati iku wọn ṣe jẹ," Oluborode sọ bẹẹ.
Kí ló mú Arsenal lulẹ̀ pẹ̀lú èròngbà rẹ̀ láti ra Osimhen àti Alvarez wá sí Premier League? Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé
Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe Arsenal ba Galatasaray sọrọ lori ati gbe Osimhen wa si ilu London lati maa gbabọọlu fawọn Gunners.
Kímò méjì ló kù kí Atinuke gbà fún ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ tó fi kú, ń kò le sọ iye owó tí a kó jọ fún-un, ọjọ́ pẹ́ tó ti ń sàìsàn, a ti sín ní àná - Owolabi Ajasa
BBC News Yorùbá kàn sí alága ẹgbẹ́ TAMPAN ní ìpínlẹ̀ Ogun láti mọ nípa àkókò ìkẹyìn Atinuke Kareem, gbajúmọ̀ òṣèré tí àìsàn jẹjẹrẹ pa.
Tani Olorun àti Sunday Igboho ni wọ́n jẹ́ ọ̀daràn tó tako òfin iléẹjọ́, ojúlówó ni ìwé àti ọlọ́pàá tó fẹ́ mú n‘Ibadan - US Imam
Ọsẹ to kọja ni awọn ọlọpaa kan ti wọn ko wọ aṣọ gbiyanju lati lọ gbe Tani Olohun nile rẹ to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo, ṣugbọn ti erongba wọn pada ja si ofo.
Àlàyé rèé lórí bí ògbóǹtarìgì agbésùnmọ̀mí, Muhammadu-Filani, ṣe rí ikú hé lọ́dọ̀ ológun tó gba onírúurú ìbọn lọ́wọ́ rẹ̀
Lasiko tawọn ikọ ologun naa n ṣiṣẹ ni ijọba ibilẹ Matazu nipinlẹ Katsina ni wọn ṣe aṣeyọri ọhun.
Ṣé àjọ EFCC kúnjú òṣùnwọ̀n láti tọpinpin ẹ̀sùn àjẹbánu bó ṣe dá ogójì òṣìṣẹ́ rẹ̀ dúró lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́?
Olukoyede sọrọ yii fawọn akọroyin nibi eto to fi n ṣami ọdun mẹta to de ipo alaga EFCC.
Ta ló ń pààrọ̀ orúkọ àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú NDC lójú òpó àjọ elétò ìdìbò, bí INEC ṣe sẹ́ pé òun kọ́?
Alaga agba fun ẹgbẹ oṣelu NDC, Sẹnetọ Moses Cleopas Zuwoghe lo pariwo yii sita lọjọ Aiku ana, lẹyin ti ajọ INEC fi orukọ awọn oludije lẹgbẹ oṣelu sita.
Kí ló ṣe Adewale Eleso, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó fi ṣiṣẹ́ abẹ, ipò wo sì ni ìlera rẹ̀ wà?
Atẹjade ti agbẹnusọ agba fun ẹgbẹ oṣere ANTP, Ọmọọba Adejonwo Oluwafemi fi sita loju opo Facebook rẹ ni Eleso ti ṣiṣẹ abẹ tori egbo oju rẹ naa.
Àwọn ọmọ ogun wa nílẹ̀ Áfríkà ló dìde ìrànlọ́wọ́ láti kojú ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ẹ́ wáyé ní Niger - Russia ṣàlàyé
Niṣe ni iro ibọn n dun lakọlakọ, ti ado oloro si n dun kaakiri ni Niamey ni owurọ kutukutu ọjọ Abamẹta gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ.
Ìdí rèé tí Dangote fi ṣe àfikún owó epo bẹntiróòlù fún ìgbà mẹ́ta láàrin ọ̀sẹ̀ kan àti ipa rẹ̀ lórí aráàlú
Ile ifọpo Dangote sọ pe afikun owo epo bẹntiroolu naa ko ṣẹyin epo rọbi ọwọnlọwọn ti ileeṣẹ naa ti ra lati oke okun papaa julọ lasiko ti owo epo rọbi lọ soke lọja agbaye.
Ọ̀rọ̀ oyè Awujale tún gba ọ̀nà míì yọ, bí igbákejì alága ìdílé Funsegbuwa ṣe wọ́ àwọn èèyàn tó ya kúrò nínú ìdílé lọ sílé ẹjọ́, bèèrè N10bn
Ni ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ ni Oloye Fassy wọ awọn eeyan naa lọ siwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun fun ẹsun ibanilorukọjẹ to si n beere fun owo itanran biliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bi owo itanran.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
A ti gba mílíọ́nù márùndínlọ́gbọ̀n Náírà owó tí Ogogo gbé fún Ìmáàmù àgbà Ilaro padà - Ẹbí Ogogo
Imam agba Mustapha ló tan imole sì ọrọ naa lowuro ojo Aje níbi ayẹyẹ fidau fun Ologbe Taiwo Hassan Ogogo to waye lonii ọjọ Aje.
Àlàyé rèé lórí ipa táwọn ikọ̀ aláàbò kó lórí báwọn Àgùnbánirọ̀ mẹ́ẹ̀dógún, aráàlú mẹ́fa, tí wọn jí gbé ní Kogi, ṣe gba ìtúsílẹ̀ àti ohun tí ààrẹ Tinubu sọ
Kii ṣe awọn agunbanirọ yii nikan lawọn ajinigbe digun ko salọ, bi ko ṣe pe wọn tun ji awọn araalu gbe pẹlu wọn, eyi ti apapọ gbogbo wọn jẹ mọkanlelogun.
Lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún, ilé ẹjọ́ kéde olórí ikọ̀ gàńfé bí ẹni tó jẹ̀bi ẹ̀sùn ikú Tupac Shakur
Adajọ ni Davis jẹbi ẹsun ipaniyan pẹlu lilo ohun ija oloro nibi ti wọn ti yibọn pa Tupac ni Las Vegas lọjọ Keje, oṣu Kẹsan-an, ọdun 1996.
Àlàyé rèé lórí ohun táwọn dókìtà nílé ìwòsàn LAUTECH ń bèèrè fún, bí ìyanṣẹ́lódì wọn ṣe wọ ọjọ́ mẹ́rin
Ẹgbẹ awọn dokita ile iwosan naa sọ pe awọn ko i tii gbọ ohunkohun lati ọdọ ijọba ipinlẹ Oyo lati ọjọ Ẹti, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ti wọn ti gunle iyanṣẹlodi naa.
A ti ṣetán láti ṣàtìlẹ́yìn fún ìjọba lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ – OPC
Ọrọ yii lo jẹyọ lọjọ Abamẹta nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti n ṣe iranti idasilẹ ẹgbẹ ọhun lọdun mejilelọgọbọn sẹyin.
Gómìnà Adeleke, mo kí ẹ kú oríire pé o wọlé fún sáà kejì àmọ́ ọ̀rọ̀ sì kù lẹ́yìn rẹ̀ - Oyebamiji, olùdíje gómìnà APC l'Osun
Oyebamiji nigba to n ba awọn ọmọ ẹyin ati alatilẹyin rẹ sọrọ fun igba akọkọ lẹyin eto idibo naa, iyẹn lọjọ Abamẹta to kọja, lo ti sọ pe oniruuru aṣemaṣe lo waye lasiko eto idibo naa.
Wo ìdí pàtàkí mẹ́rin tí Ààrẹ Tinubu kò ṣe fẹ́ kí ilẹ̀ Amẹ́ríkà fí àkọsílẹ̀ rẹ̀ nípà egbòogi olóró síta
Ninu iwe naa ni wọn ti sọ pe ofin anfaani si iroyin ati idaabo bo ẹtọ ọmọniyan yẹ ko jọba lori ṣiṣe afihan awọn akọsilẹ wọn, ati pe ko sẹnikẹni to fẹẹ mọ nipa rẹ.
Gómìnà Adeleke gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣe ìwádìí àwọn ìpànìyàn tó wáyé nílùú Ikire
Igbimọ oluwadii naa ti adajọ Majisireeti Ayokunle Shiyanbola ko sodi ni wọn yoo ṣewadii ohun to ṣokunfa ikọlu naa, ṣe agbejade iye ati orukọ awọn to fori sọta iṣẹlẹ naa, ṣewadii ohun to ikọlu ọhun ati boya o ni nnkan ṣe pẹlu iku to waye nibẹ.











































































