Kò sí orúkọ olùdíje sípò Gómìnà kankan fẹ́gbẹ́ Accord nínú àkọsílẹ̀ INEC ní ìpínlẹ̀ Oyo - Ìwádìí BBC

Oriyomi Hamzat wọ aṣọ ati fila olomi ọsan, Olakunle Busari wọ asọ dudud

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

‎Awọn Oludije mejeeji sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord, Oriyomi Hamzat ati Olakunle Busari tawọn eeyan mọ si Guduudu ti n sọ kede wi pe awọn ni yoo soju ẹgbẹ oṣelu Acoord ninu eto idibo fun ipo gomina ipinlẹ Oyo, abọ iwadii BBC News Yoruba ti fidi rẹ mulẹ pe ko si orukọ ẹnikankan ninu awọn mejeeji ninu akọsilẹ INEC.

‎Ninu ọsẹ yii ni Oriyomi Hamzat ti ṣe abẹwo si ọpọ awọn ile iṣẹ iroyin ati awọn lẹgbẹ lẹgbẹ lati rọ wọn ki wọn le dibo fun ninu eto idibo ọdun to un bọ.

‎Ṣugbon iwadii BBC News Yoruba si ọfiisi ajọ eleto idibo INEC ẹka ipinlẹ Oyo fi han wi pe ko si orukọ oludije sipo gomina lati inu ẹgbẹ oṣelu Accord kankan ninu orukọ awọn oludije sipo gomina to wa ninu akọsilẹ INEC fun eto idibo ọdun 2027.

Oṣisẹ ajọ INEC kan ti sọrọ ṣalaye wi pe,ede ayede to wa ninu ẹgbẹ oṣelu Acoord ni ko jẹ ki orukọ oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu naa ko wa lara awọn orukọ awọn ti yoo dije dupo gomina ipinlẹ Oyo lati ẹgbẹ oṣelu naa.

‎O ni, ajọ INEC yoo gbe orukọ awọn ti wọn yoo soju ẹgbẹ kọkan jade lọjọ kejila oṣu yii,eleyii ti yoo ṣe afihan awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idiboyan sipo gomina ipinlẹ Oyo.

‎Nibi ti ọrọ de duro bayii

Awọn kan ninu ọmọ ẹgbẹ oṣelu Acoord nipinlẹ Oyo Mogaji Igbinsola Paul lana ti rọ Oriyomi Hamzat lati fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ,ko si lo akọmọna rẹ Oyo npe ọ lati dije dupo gomina ipinlẹ Oyo.

‎Igbinsola ni o ti foju han wi pe Oriyomi Hamzat fẹ fi ẹgbẹ naa dokowo ni.

‎O ni awọn ti gbe ọrọ naa lọ si ile ẹjọ,abajade ile ẹjọ naa ko si ni pẹ jade,oni gbogbo igba ti awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa ba n pe Oriyomi Hamzat fun ipade ni kii yọju.

‎Oni lootọ awọn ko ti fẹnu ko lati mu ẹnití yoo dije du ipo ninu ẹgbẹ oṣelu naa, ṣugbọn oṣeṣe ki ẹgbẹ naa mu eniti wọn jo n du ipo naa lati soju ẹgbẹ oṣelu naa.

‎Oni kaka ki Kinihun ṣe akapo ẹkun ki oni kaluku ṣe ọdẹ rẹ lọọtọtọ.

Oriyomi fẹ́ já ẹgbẹ́ òṣèlú Accord gbà l'Oyo, Gudugudu ni olùdíje sípò Gómìnà fẹ́gbẹ́ wa - Ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́

Oriyomi Hamzat wọ agbada buluu pẹlu fila, Olakunle Busari wọ buba alawọ dudu ati fila

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awuyewuye lori ẹni to jẹ ojulowo oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo ko tii tan lẹyin ti igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa tun sọ pe Alhaji Oriyomi Hamzat kii ṣe oludije sipo gomina fẹgbẹ ọhun.

Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa fidi rẹ mulẹ nibi ipade awọn akọroyin kan ti wọn pe lonii Ọjọru ọjọ kẹsan an oṣu Kẹsan an yii pe Olakunle Busari, ti ọpọ eeyan mọ si Gudugudu ni ẹgbẹ yan gẹgẹ oludije sipo gomina nipinlẹ Oyo.

Igbimọ naa fikun ọrọ rẹ pe Oriyomi ti tasẹ agẹrẹ nipa pipe ara rẹ ni oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord.

Bakan naa ni wọn tun koro oju si bi wọn ti ni Oriyomi n yan awọn oloye ẹgbẹ atawọn oludije to wu u ninu ẹgbẹ lati du ọkan-o-jọkan ipo oṣelu funra ra, eyi ti ẹgbẹ ko fọwọ si.

Ninu ọrọ rẹ, akapo ẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo, Họnarebu Nurudeen Okunola, ṣalaye nibi ipade awọn akọroyin naa wi pe ''emi o ri ibi ti oludije ti n yan awọn eeyan mẹtalelọgbọn ti yoo dije fun ipo aṣoju ile igbimọ aṣofin kaakiri ipinlẹ Oyo ri.

Ṣugbọn mo mọ wi pe ti ẹnikan ba mọ nnkan daru, Ọlọrun naa mọ nnkan tun ṣe.

Nitori anfaani ti Oriyomi ni si ileeṣẹ iroyin lo jẹ ko maa pe ara rẹ ni oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo.

Amọ, mo mọ pe bi irọ ba lọ fun ogun ọdun, ọjọ kan ni otitọ yoo ba a.''

Ọgbẹni Okunola sọ pe ki ero maa tẹle eeyan lẹyin ko tumọ si pe ẹni naa yoo wọle ibo.

O ni Ọlọrun nikan lo mọ boya Gudugudu yoo wọle ibo gomina ipinlẹ Oyo.

''A o mọ boya Oriyomi fẹ fi ''Oyo n Pe Ọ'' dibo lọdun 2027, amọ, ko si nnkan ti ẹgbẹ lọwọ si ninu gbogbo nnkan ti o n ṣe''

Akapo ẹgbẹ Accord l'Oyo sọ pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu lo maa n wa nibi ipolongo ibo, tori naa ero to wa nibi ipolongo ko tumọ si pe oludije ibo kan yoo wọle.

Ọmọba Kolade Ojo to jẹ alaga ẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo ti akọwe ẹgbẹ naa sọrọ lorukọ rẹ sọ pe Oriyomi wa sinu ẹgbẹ lati ja ẹgbẹ gba.

''Oriyomi ti n sọ kiri wi pe oun ni oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord nipinlẹ Oyo, amọ, mo layọ lati sọ fun gbogbo eeyan wi pe Oriyomi kii ṣe oludipe ẹgbẹ Accord o fun ibo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2027.

Mi o mọ boya o fẹ fi ''Oyo N Pe Ọ'' dibo, ṣugbọn ko si nnkan kan ti ẹgbẹ lọwọ si ninu gbogbo nnkan ti Oriyomi n ṣe.

Ni igba ti a fẹ ṣe eto idibo abẹnu fun awọn oludije sipo gomina nipinlẹ Oyo ni a ti sọ fun Oriyomi wi pe ẹgbẹ ko ni mu ẹnikẹni lai dibo.

Amọ, Oriyomi ko yọju sibi eto idibo abẹnu ti a ṣe, Họnarebu Busari nikan lo wa nibẹ atawọn aṣoju INEC.

Oun si ni oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo, awọn ti Oriyomi lọ ba niluu Abuja lati na ọwọ rẹ soke gẹgẹ bii oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord ko le gbe Oriyomi le lori,'' akọwe ẹgbẹ lo sọ bẹẹ.