Akẹ́kọ̀ọ́ 24 jóná mọ́lé níléẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀, 21 míràn wà lẹ́sẹ̀-kan-ayé-ẹsẹ̀-kan-ọ̀run

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko din ni ọmọde akẹkọọ̀ ileẹkọ alakọbẹrẹ mẹrinlelogun ti ina jo pa ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ meji ni ilu Bukavu, lẹkun ila oorun orilẹede DR Congo lowurọ Ọjọbọ.
Gẹgẹbi ẹgbẹ ọmọogun ọlọtẹ March 23 Alliance (AFC-M23) iroyin ṣe sọ, ina naa bẹrẹ ni ileto Tshimpunda ni agbegbe Kadutu ki o to bẹrẹ si ni tan lọ si awọn ile ati ileẹkọ mejeeji yii – Ileẹkọ alakọbẹrẹ Mosala Primary school ni Kadutu ati Nongo Primary school ni Bagira. Awọn adoola ẹmi pa ina naa ṣugbọn ọwọja ọṣẹ rẹ ti gbilẹ kọ afẹnusọ. Awọn ọmọ̀debinrin mọkandinlogun ati ọmọdekunrin marun un ni ina naa jo pa, awọn nọkandinlọgbọn miran w anile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju bayii, mọkanlelogun wọn lo wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ ọmọogun ọlọtẹ lorilẹede naa, March 23 Alliance (AFC-M23) tib a awọn eeyan agbegbe naa kẹdun ti wọn si ti sọ pe iwadii yoo bẹrẹ lori ijamba naa lati le mọ ohun gan to ṣokunfa rẹ.
Bukavu ti wa labẹ akoso awọn ọmọogun ọlọtẹ M23 lati ọjọ kẹrinla oṣu keji ọdun to kọja. Ileeṣẹ eto ẹkọ ni orilẹede DR Congo ti fidi rẹ mulẹ pe ọpọlọpọ awọn akẹkọọ ati olukọ lo lugbadi ijamba ina naa. Wọn fi kun un pe "ko si ọmọ orilẹede DR Congo kankan ti ko si ni ikawọ iṣejọ rẹ" – koda ko jẹ ibi ti awọn ọmọogun ọlọtẹ n ṣakoso rẹ lọwọlọwọ. wọn tik e si ileeṣẹ eto ẹkọ lati ṣe akọsilẹ ibajẹ ti ijamba ina naa mu wa ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn ajọ ẹlẹyinjuanu lati rii pe eto ẹkọ n tẹsiwaju nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijamba ina naa waye ni ọjọ diẹ lẹyin ti ijamba ina ṣẹlẹ ni Kinshasha tii ṣe olu ilu orilẹede naa ni gbọngan nla Panacée hall ni ọjọ kẹrin si ikarun oṣu yii. Eeyan mejila lo sọ ẹmi wọn nu ninu ijamba naa – obinrin meje ati ọkunrin marun un. Ọpọlọpọ eeyan miran lo si farapa.
























