Aláànú kan kéde láti ṣe alágbàtọ́ láéláé fún ọmọ mẹ́ta tí John Olaleye bí, olùkọ́ táwọn ajínigbé pa ní Oriire

Oloogbe John Olaleye wọ aṣọ buba ankara, Dokita Kunle Adegbite n kọwọọ rin pẹlu ọkunrin ka

Oríṣun àwòrán, Kunle Adegbite/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹlẹyinju-aanu kan Dokita Kunle Adegbite ti kede pe oun yoo ṣe alagbatọ fun ọmọ mẹta ti John Olaleye, ọkan lara awọn olukọ tawọn ajinigbe ṣekupa nijọba ibilẹ Oriire fi silẹ lọ.

Dokita Adegbite ni oludije ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja fẹgbẹ oṣelu NDC fun ẹkun Ogbomoso North/Ogbomoso South/Oriire nipinlẹ Oyo

Dokita Adegbite kede wi pe nipasẹ ajọ alaanu Twindad Foundation loun yoo fi ṣe alagbatọ awọn ọmọ mẹta naa ti orukọ wọn n jẹ Daniel, Joy ati Morayo Olalere.

Ọgbẹni Adegbite kede wi pe ile awọn ọmọ alainiya ajọ Twindad to wa lagbegbe Hamama l'Ogbomoso lawọn ọmọ naa yoo maa gbe bayii.

O ni nibẹ naa ni wọn o ti maa lọ sile ẹkọ ti wọn yoo si tun ti maa jẹ awọn anfaani mii.

Olaleye jẹ ọkan lara awọn olukọ atawọn akẹkọọ tawọn janduku agbebọn ji gbe lọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un ọdun yii nile ẹkọ girama Esinele ati nile ẹkọ alakọbẹrẹ Yawota nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo.

Nigba ti wọn wa ni akata awọn ajinigbe lawọn janduku naa ran Olaleye sọrun ọsan gan an gan an.

Kunle Adegbite ati awọn ẹmẹwa rẹ n rin kọja lọ ni agboole kan

Oríṣun àwòrán, Kunle Adegbite/Facebook

''Igbesẹ lati ṣe alagbatọ awọn ọmọ oloogbe Olaleye jẹ igbesẹ titi lae''

Ninu ọrọ rẹ, Adegbite kẹdun pẹlu gbogbo ẹbi ti wọn padanu eeyan kan tabi omiran ninu iṣẹlẹ ọhun.

Dokita Adegbite ṣapejuwe iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan ọhun gẹgẹ bi eyi to bani lọkan.

Adegbite ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Facebook pe ''igbesẹ lati ṣe alagbatọ awọn ọmọ oloogbe Olaleye jẹ igbesẹ titi lae.

Awọn ọmọ yii ti darapọ mọ ẹbi TWINDAD, mo si maa ri pe wọn ni anfaani si eto ẹkọ, eto ilera ati si awọn nnkan mii lati jẹ eeyan laye.

Bo tilẹ jẹ pe a ko le mu ibanujẹ ọkan lori iku baba wọn kuro lara wọn, ṣugbọn a le ṣatilẹyin fun wọn ki ọjọ ọla wọn le dara.

Idi ti mo fi n ṣaanu ni pe mo nigbagbọ wi pe ṣiṣe adari ni ṣe pẹlu ṣiṣe iranwọ fawọn ti ko rọwọ họri.''

Dokita Adegbite fi dawọn ọmọ oloogbe mẹtẹẹta naa loju wi pe oun yoo wa pẹlu wọn.

Bakan naa ni o sọ pe oun yoo rinrin ajo pẹlu wọn lati ṣatilẹyin fun wọn lori gbogbo ohun ti wọn ba fẹ jẹ laye lọjọ iwaju.