Wo ewu tó wà nínú kí èèyàn máa fi ẹsẹ̀ lásán rìn tàbí gbé bàtà tí o bá wọ́ jáde, wọnú ilé padà
Bata wiwọ jẹ kosemani fun ọwọ eeyan, ti wọn si maa n na owo gọbọi lati fi ra bata si ẹsẹ wọn.
Awọn bata yii le wa fun iyilẹ ninu ile tabi fun imurode.
Amọ bi awọn eeyan kan se wa to fẹran bata wiwọ, ni awọn eeyan miran kii wọ bata rara, boya ninu ile tabi ni ita.
Eyi le jẹ nitori ẹsin ti wọn n sin nigba tawọn miran si wa to maa n wọ bata lọ sode amọ ti wọn kii wọn bata ninu ile.
N jẹ ẹyin maa n fi ẹsẹ lasan rin tabi ẹ maa n gbe bata ti ẹ ba wọ jade wọ inu ile?
Ẹ wa gbọ nipa awọn ewu to ba ninu igbesẹ kọọkan naa.

"O ti to ọdun marunlelọgbọn ti mo ti wọ bata sẹyin nitori ti a ba wọ asọ adura ni ti ilana ẹsin, awa kii wọ bata"
Ọkunrin kan, Moses Eniafe Dosu, lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ salaye pe oun kii wọ bata rara, boya ninu ile tabi lọ sode.
"O ti to ọdun marunlelọgbọn ti mo ti wọ bata sẹyin nitori ti a ba wọ asọ adura ni ti ilana ẹsin, awọn kii wọ bata.
Fun awa, igbesẹ aiwọ bata duro fun ifaraẹnijiya, aawẹ gbigba tiwa niyẹn.
Eyi tun tumọ si pe a ko tiju isin ta n sin, lati igba ti mo si ti n fi ẹsẹ rin, ko si ọjọ kan ti nnkan gun mi lẹsẹ tabi farapa ri."

Ero awọn eeyan se ọtọọtọ lori wiwọ bata wọ inu ile
Obinrin mii, Akinyemi Olaide, to ba BBC News Yoruba sọrọ ni awọn kii wọ bata wọnu ile rara.
"Ti a ba lọ sita, a maa n bọ bata sẹnu ọna ni, ko to di pe a maa fi ẹsẹ nu asọ to wa lẹnu ọna, ti a maa fi wọnu ile.
Idi ni pe awọn bata yẹn ti maa n ko awọn kokoro kekeke ti a ko le foju ri, gẹgẹ bi emi ti mo si ni ọmọde, o seese kawọn kokoro naa wọ ara ọmọ kekere, ti mo ba wọ bata wọ inu ile."
Ẹlomiran to tun ba BBC News Yoruba sọrọ, Olakunle Orobiyi ni oun maa n wọ bata wọnu ile ni toun tori oun ko ri bi igbesẹ ti ko dara
"Mo jẹ eeyan kan to jẹ pe n ko fẹran ki n maa fi ẹsẹ tẹ ilẹ lai jẹ pe mo wa lori ibusun ti mo ti fẹ sun.
Ibikibi ti mo ba n lọ, ni mo maa n wọ bata mi lọ titi ti maa fi wọnu yara ibusun mi lati sun.
Ti mi ba ri pe bata yẹn ko idọti, ma tun inu ile se, maa gba inu ile."
Awọn ewu to wa ninu ka maa fi ẹsẹ lasan rin kiri tabi gbe bata ta fi rin nita wọnu ile - Dokita
N jẹ awọn ewu tabi aleebu wo lo wa ninu ki eeyan maa fi ẹsẹ lasan rin tabi ewu to wa nibẹ?
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, dokita onimọ isegun oyinbo kan, Olajumoke Oyedeji ni lara ewu to wa nibẹ ni pe a le ko idọti aifojuri wọ inu ile.
"Ti a ba n gbe bata ti a gbe lọ sita, wọ inu ile, gbogbo awọn idọti aifojuri to ti fi ẹsẹ rẹ gbe nita, to ba gbe wọle.
Ti o ba ni ọmọ kekere, to si n ra lọwọ, ọmọ̀ naa yoo dawọ le, yoo si ti awọn nnkan naa bọ ẹnu, ti aisan yoo si wọnu agọ ara iru ọmọ bẹẹ.
Awọn to wọ bata lọ si ọja, ibisẹ, ti wọn ba dele, ki wọn bọ bata yẹn sita, ki wọn si maa wọ bata ti wọn ba n wọ ninu ile.
Fun awọn eeyan to ba n fi ẹsẹ rin, ti wọn ba de ile, ki wọn maa fọ ẹsẹ wọn daadaa, ki wọn to da ẹsẹ wọ inu ile.






