Ìdí tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fi ṣẹ́wélé àṣẹ adájọ́ tó ní kí INEC yọ orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú Oriyomi, Adeleke àti Atiku kúrò nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀

Atiku Abubakar, Oriyomi Hamzat ati Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X/Atiku Abubakar/X/Ademola Adeleke/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ilẹ ẹjọ kotẹmilọrun ti ṣẹwele aṣẹ ile ẹjọ giga apapọ l'Abuja to ni ki ajọ eleto idibo INEC yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu ADC, Accord, ZLP, AA ati APP kuro ninu awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ninu eto idibo to n bọ.

Igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta ti Adajọ A. B. Mohammed dari bu ẹnu ẹtẹ lu bi Adajọ Peter Lifu ile ẹjọ giga apapọ l'Abuja ṣe dajo tako aṣẹ ile ẹjọ to jade lọjọ kejilelogun oṣu Karun un to kọja; eyi to sọ pe ko gbọdọ gbe igbesẹ lori ẹjọ to wa niwaju rẹ.

Awọn adajọ mẹtẹẹta naa sọ pe iwa to tako eto idajọ ni Adajọ Lifu hu pẹlu idajọ ti o gbe kalẹ.

Igbimọ oludajọ naa ni nnkan ti Adajọ Lifu ṣe tako ilana eto idajọ ati iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.

''Igbesẹ ile ẹjọ giga lati gbe idajọ kalẹ lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti paṣẹ idaduro lori ọrọ naa jẹ iwa to ko kudiẹ kaato eyi to lodi si ilana eto idajọ.

Koda, ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti sọ pe iru adajọ to ba huwa bayii ko yẹ lati maa ṣiṣẹ adajọ tori iwa jagidijagan ni eleyii tumọ si ninu eto idajọ.

Ile ẹjọ ni lati maa gbiyanju ki orukọ wọn ma bajẹ, ile ẹjọ kotẹmilọrun ni aṣẹ lori nnkan ti ile ẹjọ giga ba n ṣe lori ọrọ to ba wa niwaju rẹ.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun si le paṣẹ lati ri wi pe gbogbo nnkan lọ ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin.

Idi niyii ti ile ẹjọ yii fi ṣẹwele aṣẹ ile ẹjọ giga apapọ to ni ki ajọ INEC yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu marun un kuro ninu akọsilẹ rẹ,'' igbimọ oludajọ ṣalaye.

Ṣaaju ni ajọ eleto idibo INEC funra rẹ ti sọ fun ile ẹjọ wi pe idajọ ti Adajọ Lifu gbe kalẹ jẹ iyalẹnu foun.

Koda, INEC tun sọ pe ninu iwe iroyin loun ti ri iroyin naa ka tori ile ẹjọ giga ko sọ nnkan foun nipa idajọ naa.

Ajọ eleto idibo Naijiria ni oun mọ nipa aṣẹ ile ẹjọ to jade lọjọ kejilelogun oṣu Karun un, eyi to ni ile ẹjọ giga ko gbọdọ tii gbe idajọ kalẹ lori ọrọ to wa niwaju rẹ bayii.

Ni bayii, orukọ ẹgbẹ oṣelu maraarun un ADC, Accord, ZLP, AA ati APP tọrọ kan si wa ni akọsilẹ INEC titi ti igbẹjọ ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn pe yoo fi waye.

Ẹgbẹ́ òṣèlú Adeleke àti Oriyomi fapá jánú lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ní kí INEC yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ rẹ̀

Oriyomi Hamzat ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oriyomi Hamzat/Adeleke

Ẹgbẹ oṣelu ADC ati Accrod ti bu ẹnu atẹ lu idajọ ile ẹjọ giga kan niluu Abuja to ni ki ajọ eleto idibo, INEC, fa orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu naa yọ ninu akọsilẹ rẹ nitori wọn ko ba ofin mu.

Lara awọn to bu ẹnu atẹ lu idajọ naa ni gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun to juwe idajọ ọhun gẹgẹ bii aṣilo ẹka eto idajọ ni Naijiria.

O ni ko si ohun ti yoo yẹ kikopa ẹgbẹ oṣelu Accord ninu eto idibo gomina ti yoo waye ninu oṣu Kejọ ọdun yii ni ipinlẹ naa.

Ẹgbẹ awọn aṣofin nigba kan ri, National Forum of Former Legislators, lo pe ẹjọ naa lati bere lọwọ ile ẹjọ pe ṣe INEC lẹtọọ lati wọgile awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn kuna lati ni awọn amuyẹ to wa ni abala 225A ti ofin ọdun 1999, eyii ti wọn ṣatunṣe rẹ lọdun 2022.

Nigba ti awọn alakoso ẹgbẹ Accord yoo sọrọ, wọn ni idajọ naa ko ba ofin mu latari pe o tako idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to ti waye ṣaaju.

Accord ni idajọ ọhun waye bo tilẹ jẹ pe idajọ kan ti waye ṣaaju, eyii to tako idajọ ile ẹjọ giga tuntun yii.

Ẹgbẹ oṣelu naa fi kun pe awọn ti bẹrẹ igbeṣe lati pe idajọ naa nija nile ẹjọ laipẹ.

Accord ni idajọ ọhun ko fo oun laya nitori oun jawe olubori ninu eto idibo sipo kansẹlọ to waye ni Jigawa lẹnu lọlọ yii.

Lẹyin naa ni wọn ni ki awọn ọmọ ẹgbẹ naa atawọ alatilẹyin awọn ma foya nitori wọn yoo kopa ninu eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ekiti ati ti ipinlẹ Osun to n bọ laipẹ yii.

Iwọyin ni awọn ẹgbẹ oselu ti ọrọ naa kan:

  • African Democratic Congress (ADC)
  • Accord Party (AP)
  • Action Alliance (AA)
  • Action Peoples Party (APP)
  • Zenith Labour Party (ZLP

Ofin wo gan ni ile ẹjọ sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun tẹ loju mọlẹ?

Gẹge bii ohun ti adajọ to gbọ ẹjọ ọhun, Peter Lifu sọ, awọn ẹgbẹ oṣelu naa kọlu abala 225A ti ofin ọdun 1999 eyii ti wọn ti ṣe atunṣe si.

Abala ofin naa fun INEC lagbara lati wọgile orukọ ẹgbẹ oṣelu ninu iwe rẹ

  • Ti wọn ba kuna lati jawe olubori ninu eto idibo ni ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ tabi ijọba ibilẹ.
  • Ti wọn ba kuna lati ko ida 25% ibo ni ipinlẹ kan lasiko idibo Aarẹ, atawọn amuyẹ mii.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn to pe ẹjọ ọhun sọ, awọn ẹgbẹ oṣelu naa kuna lati ni awọn amuyẹ naa ninu awọn eto idibo to waye lẹnu lọlọ yii.

Ile ẹjọ ti wa paṣẹ ki INEC yọ orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu naa kuro ninu iwe rẹ, o tun paṣẹ ki INEC ma jẹ ki wọn kopa ninu eto idibo ọjọ iwaju bii eto idibo to n bọ lọdun 2027.

Ilé ẹjọ́ ní kí INEC yọ orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú Atiku, Oriyomi àti ẹgbẹ́ mẹ́ta mii kúrò nínú àkọsílẹ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú

Oriyomi Hamzat fọwọ lẹran, Atiku Abubakar n sọrọ pẹlu ẹrọ gbohungbohun

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/X/Atiku Abubakar/X

Ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja ti paṣẹ fun ajọ eleto idibo INEC pe ko yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu ADC, Accord ati ẹgbẹ oṣelu mẹta mii kuro ninu awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ninu eto idibo 2027 to n bọ.

Awọn ẹgbẹ oṣelu mẹta toku ni ẹgbẹ APP, ẹgbẹ oṣelu AA, ati ẹgbẹ ZLP.

Adajọ Peter Lifu lo paṣẹ naa nile ẹjọ giga apapọ l'Abuja lọjọ Aje ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹfa yii.

Ṣaaju ni igbimọ awọn aṣofin tẹlẹri ti beere pe ki ile ẹjọ sọ boya ajọ eleto idibo INEC lagbara labẹ ofin lati yọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ba kuna lati ṣe nnkan ti abala 225A iwe ofin orilẹede Naijiria sọ kuro, eyi to wa ni ibamu pẹlu atunṣe ofin eto idibo Naijiria ti ọdun 2022.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbimo awọn aṣofin tẹlẹri naa sọ fun ile ẹjọ wi pe awọn ẹgbẹ oṣelu marun un yii ti kuna lati maa tẹsiwaju gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria.

Lara awọn nnkan amuyẹ tawọn aṣofin naa sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu marun un naa kuna lati ni, ni ida 25% ibo nipinlẹ kan lasiko eto idibo aarẹ to kọja.

Amuyẹ mii ni pe awọn ẹgbẹ oṣelu yii gbọdọ ni aṣoju kan ti araalu dibo yan yala ni ijọba ibilẹ tabi ipinlẹ tabi nile aṣofin agba l'Abuja.

Awọn olupẹjọ naa sọ fun ile ẹjọ wi pe ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin yoku fidirẹmi ninu ibo gbogbogbo ọdun 2023 ati ninu atundi ibo to waye debi wi pe wọn ko ni aṣoju kankan ti araalu dibo yan.

Awọn aṣofin tẹlẹ ri naa sọ pe bi ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin mii ṣe wa lara awọn ẹgbẹ oṣelu to fẹ dije ninu eto idibo to n bọ lodi sofin orilẹede Naijiria ati ofin eto idibo.

Lẹyin naa ni wọn rọ ile ẹjọ pe ki o yọ orukọ awọn ẹgbẹ marun un naa kuro ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.

Bakan naa tun ni awọn olupẹjọ tun rọ ile ẹjọ lati fofin de awọn ẹgbẹ oṣelu marun un naa wi pe wọn o gbọdọ kopa ninu ipolongo ibo ati eto idibo ọdun 2027 to n bọ.

Wọn tun rọ ile ẹjọ wi pe ko paṣẹ fun ajọ INEC pe ko gbọdọ ni ibaṣepọ kankan pelu awọn ẹgbẹ naa mọ.

Idajọ yii yoo ṣakoba fun Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, to fẹ dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC ninu eto idibo ọdun 2027.

''Awọn aṣoju ijọba to wa lode ni ko fẹ ki ADC kopa ninu ibo 2027''

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu ADC to jẹ ẹgbẹ Atiku Abubakar ti sọ pe ile ẹjọ fẹ lo ara rẹ lati ṣakoba fun ijọba awaarawa pẹlu idajọ ti ileẹjọ apapo l'Abuja gbe jade.

Ẹgbẹ naa sọ pe idajọ ti Adajọ Peter Lifu gbe kalẹ buru jai, o si le da rogbodiyan silẹ lagbo oṣelu.

Ẹgbẹ ADC sọ ninu atẹjade to fi sita pe idajọ ile ẹjọ giga apapọ naa tako iwe ofin Naijiria.

Lori ọrọ ti awọn aṣofin tẹlẹ ri naa sọ fun ile ẹjọ wi pe ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin mii pe wọn o ni amuyẹ lati wa lara awọn ẹgbẹ ti yoo kopa ninu eto idibo to n bọ, ADC sọ pe ajọ INEC funra rẹ ti fontẹ lu ẹgbẹ ADC loṣu Karun un to kọja.

Ẹgbẹ ADC ni kii ṣe ajọ kan lo maa sọ pe ki INEC yọ orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu kan kuro ninu akọsilẹ ẹgbẹ oṣelu.

Wọn ni ọrọ ofin lọrọ naa, eyi ti INEC funra rẹ gan an ko si ri ẹsun kankan ka si ẹgbẹ naa lẹsẹ.

ADC ni nnkan to yani lẹnu ni wi pe adajọ Lifu mọ wi pe ẹjọ kan wa nile ẹjọ kotẹmilọrun tẹlẹ eyi ti ko tii ni iyanju ki o to gbe idajọ tiẹ kalẹ.

Ẹgbẹ oṣelu Atiku ni ọrọ naa ti lọwọ oṣelu ninu, wọn ni awọn agbodegba ẹgbẹ APC lo wa nidii ọrọ naa.

Ninu ọrọ tiẹ, oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo, Oriyomi Hamzat, ti sọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ni ọrọ idajọ ileẹjọ giga apapọ l'Abuja to ni ki wọn yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu naa kuro ninu akọsilẹ INEC ti le ni iyanju.

Oriyomi ni ile ẹjọ ko le da nnkan tawọn araalu n fẹ duro.

Oriyomi sọ pe ẹjọ naa wa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun tẹlẹ, ati pe awọn n reti nnkan idajọ ile kotẹmilọrun lori ọrọ naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2