"Inú ìrora ńlá la wà" Ọmọbìnrin Ọ̀gágunfẹ́yìntì Rabe Abubakar, táwọn agbébọn jí gbé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, sọ̀rọ̀ lórí ikú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Wọn ti sin oku Ọgagunfẹyinti Rabe Abubakar to ku sinu ahamọ awọn ajinigbe lẹkun iwọoorun ariwa orilẹede Naijiria.
Aarẹ Tinubu ti kọminu lori iṣẹlẹ naa, o siti ba awọn ẹbi kẹdun pẹlu ileri pe awọn igbesẹ to lagbara yoo waye lati kọlu awọn ẹgbẹagbesunmọmi to n ṣọṣẹ lagbegbe gbogbo kaakiri orilẹede Naijiria.
Ninu ọrọ ti ọmọbinrin oloogbe naa, Bilikisu Rabe Abubakar sọ fun BBC News, O ni inu irora nla lawọn ẹbi oloogbe naa wa bayii lẹyin ijinigbe ati iku rẹ.
Bilikisu ṣalaye pe wọn sin oku ọgagunfẹyinti naa ni irọlẹ ọjọ kan naa ni ibamu pẹlu ilana ẹsin musulumi.awọn alaṣẹ sọ pe inu ahamọ awọn ajinigbe naa lẹyin ti ilera rẹ mẹhẹ lori ohun ti wọn sọ pe o rọ mọ aisan itọ ṣuga ati ẹjẹ riru.
Ipinlẹ Katsina ni wọn ti ji ọgagunfẹyinti naa ati iyawo rẹ gbe.
Titi di asiko yii, ko tii si ẹni le sọ ni pato ibi ti iyawo ọgagun agba naa, Hajiya Amina Abubakar wa. Ẹbi rẹ sọ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ abo gbogbo ti fi ọkan awọn balẹ pe wọn n gbe gbogbo igbesẹ lọwọlọwọ lati gba itusẹ rẹ.
Ọ̀gágun fẹ̀yìntì Rabe Abubakar táwọn agbébọn jí gbé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ ti kú sí àkàtà àwọn jàndùkú ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Ọgagunfẹyinti nileeṣẹ ologun Naijiira, Maj Gen Rabe Abubaka, tawọn agbesunmọmi ji gbe pẹlu iyawo rẹ nipinlẹ Katsina lapa ariwa Naijiria ti ku bayii si akata awọn janduku ajinigbe.
Adari eto iroyin fun ileeṣẹ ologun Naijiria, Maj Gen Samaila Uba, lo fi idi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti o fi sita lonii ọjọ Abamẹta ọjọ kẹtala oṣu Kẹfa yii.
Ọgagun Uba ni pẹlu ibanujẹ ọkan ni ileeṣẹ ọmogun Naijiria fi kede iku ajagunfẹyinti Abubakar.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ologun ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi atawọn akẹgbẹ Ọgagun fẹyinti naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun Naijiria ṣapejuwe ajagunfẹyinti Abububakar gẹgẹ bi akinkanju to fi tọkan tọkan sin orilẹede Naijiria ninu iṣẹ ologun.
O ni Ọgagun naa ti figba kan ri jẹ agbẹnusọ fun ikọ AFN nileeṣẹ ologun nigba aye rẹ.
Bakan naa ni Ọgagun to doloogbe naa tun kopa ribi ribi ninu igbogun ti awọn agbesunmọmi ni Naijiria.
Ọgagun Samaila ni awokọṣe rere ni Ajagunfẹyinti Abubakar jẹ fun ọpọ eeyan pẹlu bi o ṣe jẹ olufọkansin nigba to ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọmogun Naijiria.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun ko ṣai fidii rẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọmogun mọ-ọn mọ pinnu lati ma sọ nnkankan lori akitiyan lati doola ọgagun naa ko to di pe o jade laye.
Alukoro ileeṣẹ ọmogun fikun ọrọ rẹ pe iku Ọgagunfẹyinti Abubakar ti tun fawọn ọmogun lagbara sii lati tẹsiwaju pẹlu ija tawọn n gbe koju awọn agbesunmọmi.
O ni awọn ko ni kaarẹ ninu akitiyan awọn lati daabo bo ọmọ orilẹede Naijiria.
''Ni bayii, iṣẹ si n lọ lọwọ lati fọwọ ofin mu gbogbo eeyan to wa nidii iku ọgagun Abubakar ati gbogbo awọn agbesunmọmi to n dunkoko mọ alaafia orilẹede Naijiria.
A fi n dawọn ọmọ Naijiria loju wi pe a ko ni sinmi titi ti a o fi ṣẹgun awọn agbesunmọmi ti alaafia yoo si jọba ni Naijiria,'' alukoro ileeṣẹ ologun Naijiria lo sọ bẹẹ.

























