Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ l'Osun ṣáájú ìbò gómìnà tó ń bọ̀, ọlọ́pàá mú akọ̀wé ijọba, Adeleke ní aráàlú kò ní gbà

Oríṣun àwòrán, Gov Ademola Adeleke/X
Ibẹru bojo ti gbalẹ nipinlẹ Osun ṣaaju eto idibo Gomina to n bọ, lẹyin ti awọn ọlọpaa ya wọ ile akọwe ijọba ipinlẹ naa, Teslim Igbalaiye, ti wọn sì fọwọ mu un ati eeyan marun un mii.
Ijọba Gómìnà Ademola Adeleke sí ti fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa wi pe wọn yan ẹgbẹ oṣelu alatako sọju bi eto idibo Gomina ipinle Osun ṣe n kan ilẹkun gbọngbọn.
Amọ, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn rí owo to to ₦4,810,500, kaadi idibo meji, iwe àkọsílẹ oludibo at'awọn nnkan mii to lodi si ofin eto idibo nile akọwe ijọba ipinlẹ Osun.
Amọ, ìgbìmọ̀ olupolongo ibo fun Gómìnà Adeleke ti sọ pe irọ to jinna si otitọ ni ileeṣẹ ọlọpaa n pa.
Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkan lára àwọn t'awọn fọwọ́ òfin mú nílé akọwe ijọba ipinlẹ Osun jẹ afurasi ti ọlọ́pàá n wa, Oladele Abiodun, lori ẹsun iwa ọdaran.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Abiodun Ojelabi, sọ ninu atẹjade kan ti o fi sita pe awọn nnkan mii táwọn tun ri nile akọwe ijọba ipinlẹ Osun ni ẹrọ kọmputa meji, ẹrọ tí wọn maa fi n ṣe ẹda iwe kan ati ẹrọ ti wọn fi n tẹ iwe kan nile akọwe ijọba ipinlẹ Osun.
Awọn eeyan mii ti wọn tun fọwọ́ òfin mú ni Akande Taiwo ẹni ọgọta ọdun, Adeyemo Lukman, ẹni ọdún marundinlaadọta, Olaoye Muftau, ẹni aadọta ọdun ati Aderemi Musliu to jẹ ọmọ ogoji ọdun.
Ojelabi sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ṣiṣẹ iwadii lori ọrọ kan ti wọn gbọ ni wọn fi ṣawari awọn eeyan yii nile akọwe ijọba ipinlẹ Osun.
"Gbogbo àwọn nnkan ti a ri gba nile akọwe ijọba Ipinlẹ Osun ni o ti wa lọdọ wa bayii fun iwadii siwaju sii.
Owo ti a ri ati iwe orukọ oludibo sọ nipa ẹsun to lodi sofin eto idibo.
Nigba ti iwadii si n lọ lọwọ, awọn nnkan ti a ri bayii n tọka si ẹsun fifun awọn oludibo ni riba tabi ibo rira eyi to tako abala 121 ofin eto idibo Naijiria ọdun 2022.
Gbigba awọn ọdaran ti ijọba n wa sile naa lodi si ofin,'' agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa lo sọ bẹẹ.
''Awọn eeyan ipinlẹ Osun ko ni gba ki ẹnikẹni dunkoko mọ wọn ''
Ẹwẹ, Gomina Ademola Adeleke ti sọ pe awọn eeyan ipinlẹ Osun ko ni gba ki ẹnikẹni dunkoko mọ wọn tori ko tii ṣẹlẹ ri ninu itan.
Gomina Adeleke ni awọn eeyan ipinlẹ naa ṣetan lati daabo bo ẹtọ wọn.
''Bi eto idibo gomina ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ to n bọ ti n kan ilẹkun, mo ni igboya wi pe ko si ẹni to le dunkoko mọ awọn eeyan ipinlẹ Osun.
Nnkan tawọn eeyan ba fẹ ni yoo ṣẹlẹ, gbogbo iwadii ti a ti ṣe lo n tọka si pe ẹgbẹ oṣelu Accord ni yoo bori ninu eto idibo to n bọ.
Eyi yoo ṣẹlẹ tori awọn araalu ti ri ipa ijọba to wa lode.
Gbogbo iṣẹ ti a ti ṣe lẹka eto ẹkọ to fi de ẹka eto ilera, igbayegbadun awọn oṣiṣẹ ati sisan owo oṣisẹfẹyinti jẹ nnkan ti gbogbo eeyan ri soju.
Ni agbara Ọlọrun pẹlu atilẹyin awọn araalu, ijọba wa maa tẹsiwaju lori awọn iṣẹ ti a ti ṣe yii,'' Gomina Adeleke lo sọ bẹẹ.
Adeleke ni ọjọ ọla ipinlẹ Osun dara gan an, nigba to tun rọ awọn araalu lati wa lojufo lasiko eto idibo to n bọ ki wọn si ri pe ibo wọn di kika.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post


























