Wo àwọn ibi tí Egúngún Olóòlù yóò lọ nílùú Ibadan, àwọn ọjọ́ tí yóò wà láwọn agbègbè náà àti ohun márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Egúngún olóòlù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2027 ni egungun Oloolu yoo bẹrẹ si n jade niluu Ibadan.
Ṣaaju asiko yii ni Kabiesi Olubadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja ti kọkọ kede ninu atẹjade kan pe ki awọn araalu, paapaa awọn obinrin, ṣora fun Egungun naa.
Ẹwẹ, ọrọ Kabiesi ọhun ko dun mọ awọn Musulumi kan ninu lẹyin ti wọn sọ pe ko tọ ki Egungun di lilọ-bibọ awọn obinrin lọwọ laarin ilu paapaa nibi ti aye laju de lonii.
Ojojumọ ni Egungun naa yoo maa jade lati ọjọ Aje.
Atẹjade Olubadan sọ pe "Eewọ ni fun awọn obirin lati foju ganni Egungun Oloolu; fun idi eyii, a gba awọn obinrin lamọran ki wọn yẹgo fun Egungun ọhun ni gbogbo ọna fun anfani ara wọn.
Bi irinajo Oloolu yoo ṣe lọ laarin ọsẹ yii
Ọjọ Aje ni Oloolu yoo ṣadura fun Olubadan, awọn oloye atawọn alabaṣiṣẹ rẹ, to fi mọ gbogbo ara ilu Ibadan ko to lọ ṣabẹwo si Otun Olubadan, Ọba Eddy Oyewole nile rẹ lagbegbe Foko.
Lọjọ Iṣẹgun ni yoo ṣabẹwo si gomina Seyi Makinde nile ijọba to wa ni Agodi, yoo tun lọ si Aliiwo, Yemetu, ọja Oje, Isale -Afa, Oke Aremo, Popo – Yemoja, ọja Bode, Molete, Isale-Ijebu, Elekuro, Kobomoje ati Oranmiyan.
To ba di Ọjọru to jẹ ọjọ to kẹyin ọdun Oloolu ni yoo lọ si Aperin, Agugu, Iyana Idi-Iroko, Awotunde Jegede, Itamerin-Gangansi, ati Babanla.
Kabiesi Olubadan ti kilọ fun awọn atọkun Egungun naa ati gbogbo awọn ti yoo tẹle ki wọn ṣọra fun jagidijagan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹbi aafin Olubadan ṣe ṣe ikede rẹ, bayii ni irin Egungun Oloolu yoo ṣe lọ si lasiko ajọdun Egungun naa ni ilu Ibadan.
Ọjọ Aje ni ọdun Oloolu bẹrẹ pẹlu aisun ọdun Oloolu. Oloolu yoo kọkọ lọ ki Kabiyesi Olubadan ni aafin rẹ to w ani Oke Arẹmọ nibi ti yoo ti wure fun Olubadan, awọn igbimọ Olubadan, awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan atawọn olugbe inu ilu naa. Lẹyin eyi ni yoo kọwọrin lọ si ile Ọtun Olubadan, Ọba Eddy Oyewọle ni Fọkọ ni ilu Ibadan.
Agogo mẹrin irọlẹ ni Egungun naa yoo maa jade bẹrẹ lati Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu keje titi di ọjọbọ ọgbọn ọjọ oṣu keje.
Ọjọ Iṣẹgun
Awọn agbegbe ti yoo de:
- Ile Ijọba ni agbegbe Agodi
- Aliiwo
- Yemetu
- Oje Market
- Olubadan Palace
- Isale-Afa
- Oke Aremo
- Popo-Yemoja
- Bode Market
- Molete
- Isale-Ijebu
- Elekuro
- Kobomoje
- Oranyan
Ọjọru
- Ojagbo
- Alafara Olubadan
- Ita-Bale
- Ogboriefon
- Labo
- kudeti
- Ile tuntun/Oke odo
- Kobomoje
Ọjọbọ
- Ile-Aperin
- Agugu
- Iyana Idi-Iroko
- Awotunde Jegede
- Itamerin-Gangansi
- Babanla
Wo awọn ohun mẹfa to yẹ ki o mọ nipa Egungun Oloolu Orisun Oloolu
1. Itan Oloolu
Itan Oloolu ṣe lati igba ti ogun kan ti waye niluu Ogbagi, nipinlẹ Ondo.
Asiko ogun naa ni jagunjagun kan, Ayorinde Aje ṣegun rẹ to si mu Oloolu wa siluu Ibadan.
Lasiko ti wọn n bọ lọna Ibadan ni Ayorinde paṣẹ ki wọn ge ori iyawo ẹni to ko ẹru Oloolu lẹyin to sọ pe oun ko le tẹsiwaaju ninu irinajo naa.
2. Agbara inu aṣa ati ọwọ
Ninu igbagbọ Yoruba, Egungun igba iwasẹ ni Oloolu to jẹ eyii to maa n so awọn araalu pọ mọ awọn baba nla wọn.
Igbagbọ wa pe Egungun naa ni eyii ti wọn bẹru julọ niluu Ibadan ati ni gbogbo ilẹ Yoruba.
3. Ilana etutu rẹ
Oniruru eewọ lo rọ mọ Egungun naa: fun apẹerẹ, ẹni to n gbe Egungun ọhun gbọdọ yẹra fun iyawo rẹ fun ọgbọn ọjọ gbako ṣaaju ayẹyẹ ọhun.
Egungun naa ko gbọdọ wọ bata to ba ti wọ inu ẹku, ko si gbọdọ gbe ẹru mii yatọ si ẹku to wọ, ninu eyii ti agbari obinrin wa lara rẹ.
Eewọ tun ni lati pe Egungun Oloolu nija, bẹẹ si ni Egungun mii ko gbọdọ gbena woju re ni igboro.
4. Asiko ọdun Egungun naa
Ọdọdun ni wọn maa n ṣe ọdun Oloolu ninu osu Keje. Lara awọn ibi pataki ti Oloolu maa n ṣabẹwo si lasiko naa ni Popo Yemoja, Beere, ati Oja'ba.
Lasiko ọdun Oloolu, eewọ ni fun Egungun mii lati jade.
5. Awọn eewọ ati igbagbọ igba iwasẹ
Igbagbọ wa pe ẹni to ba kọkọ foju gaani Oloolu le ṣaisan fun ọjọ pipẹ, irufẹ ẹni bẹẹ si le jade laye ti wọn ko ba tete ṣe awọn etutu kan to yẹ fun un .
Eewọ ni fun obinrin lati foju ri Oloolu.
Igbagbọ wa pe eyikeyi obinrin to ba foju ganni Oloolu ko ni ri nnkan oṣu rẹ mọ, nigba mii, irufẹ obinrin bẹẹ le di ẹni ti wọn n gbeka tabi ko jade laye.


























