MURIC, ẹgbẹ́ Mùsùlùmí nàká àìtọ́ síjọba Oyo pé ó ló ìjínigbé Ogbomoso tako Islam, ìjọba sọ ìdí tí kò ṣe ní fèsì sí ẹ̀sùn náà

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Ọrọ ijinigbe to waye ni ipinlẹ Oyo ati ẹsun pe awọn ajinigbe n beere fun ifẹsẹmulẹ ofin Sharia nipinlẹ Oyo, ti bi nnkan miran.
Eyi ri bẹẹ bi ẹgbẹ MURIC to n ja fun ẹtọ awọn musulumi ti fẹsun kan ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo wí pe o n lo iṣẹlẹ ijinigbe to waye l'Ogbomoso lati tako ẹṣin Islam at'awọn musulumi.
Alakoso agba ẹgbẹ MURIC, Ọjọgbọn Ishaq Akintola, sọ ninu atẹjade to fi sita lonii ọjọ Isẹgun pe bibeere t'awọn kan ni awon agbebon n beere fún lilo ofin Shariah lara nnkan ti wọn fẹ kí ìjọba ṣe k'awọn to le tu awon akẹkọọ àtàwọn olùkọ́ to wa lakata awon silẹ mu ifura dani.
Ọjọgbọn Akintola sọ ninu atẹjade náà wi pe "bi awọn janduku agbébọn ṣe n pe fun lilo ofin Shariah nipinlẹ Oyo ti jẹ kí a gbagbọ pe ijoba Gomina Seyi Makinde n lo iṣẹlẹ ijinigbe to ṣẹlẹ lati tako awọn musulumi ni ilẹ Yoruba ni.
MURIC tẹsiwaju pe "A le sọ pe bi ọrọ naa ṣe ri niyi nitori ipinlẹ Oyo ni iṣẹlẹ yii ti waye labẹ aṣẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo.
Eyi si tumọ si pe ijoba ni ipa tí wọn n ko ninu idunadura to n lọ lọwọ pẹlu awọn ajinigbe."
MÚRIC ni ìwọ́de t'awọn oniṣẹṣe kan ṣe nílùú Ibadan lẹyìn tí fídíò kan kọkọ jade lori nnkan t'awọn agbébọn n beere fún fidi rẹ múlẹ pe lóòótọ́ ní ìjọba n lo ọrọ naa lati tako awọn musulumi.
"Ijọba ìpínlẹ̀ Oyo ni lati sọ fún gbogbo eeyan boya lóòótọ́ ni awọn ajinigbe béèrè fun lilo ofin Shariah nipinlẹ Oyo"
MURIC sọ pe ninu fídíò naa lawọn kan ti sọ pe "ẹ jẹ ka tako Islam, ẹ tako ẹṣin apaayan.
Ọjọgbọn Akintola ni idi niyi ti ẹgbẹ MURIC ṣe fẹsun kan Gomina pe oun lo n lo awọn eeyan lati tako awọn musulumi.
Ẹgbẹ MURIC wa ke pe ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo lati sọ fún gbogbo eeyan boya lóòótọ́ ni awọn ajinigbe béèrè fun lilo ofin Shariah nipinlẹ Oyo, ki wọn to o le fawon akẹkọọ àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n ji gbe silẹ.
Ọjọgbọn Akintola sọ pe t'awọn ajinigbe ba n tẹle ofin Shariah ni, wọn ko ni maa ji àwọn èèyàn gbe lapa Ariwa Naijiria nibi ti won ti n lo òfin Shariah.
MÚRIC ni ẹnìkankan ko le pe aja ni ọbọ fawọn Musulumi.
"Ijọba ti pinnu lati maṣe sọ nnkankan sita lori ọrọ iṣẹlẹ ijinigbe Ogbomoso"
Ẹwẹ, Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Oyo, Ọmọba Dotun Oyelade, ti sọ fun BBC Yoruba wi pe lati ọjọ ti wọn ti ji awọn akẹkọọ ati olukọ lọ ni Esinele ati Yawota l’Ogbomoso ni ijọba ti pinnu pe oun ko ni maa ṣe arohunbọhun pẹlu ẹnikankan lori iṣẹlẹ naa.
Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ijọba ko ni da ẹnikẹni to ba n kọ nnkankan lori iṣẹlẹ naa lohun.
Ọmọba Oyelade ṣo pe nnkan ẹyọ kan to jẹ ijọba Gomina Seyi Makinde logun ni bi awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe l’Ogbomoso yoo ṣe pada wale ni alaafia.
‘’Ijọba ti pinnu lati ma sọ nnkankan sita lori ọrọ yii, amọ, iṣẹ n lọ lọwọ lori ati doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn wa lakata awọn ajinigbe.
Mo fi n da araalu loju wi pe awọn eeyan ipinlẹ Oyo yoo pada rẹrin-in lori iṣẹlẹ ijinigbe yii.
Ipinlẹ Oyo yoo sí jẹ ipinlẹ akọkọ nibi ti ọrọ awọn ajinigbe yoo ti lojutuu ni gbogbo Naijiria.’’
"Ijọba ko ni fesi si ọrọ MURIC tori ọrọ naa ko le ṣeranwọ lati doola awọn ti wọn ji gbe"
Lori ọrọ ti MURIC sọ pe ijọba ipinlẹ Oyo n lo ọrọ Shariah lọna aitọ lori iṣẹlẹ ijinigbe Ogbomoso, kọmiṣọna ni ijọba ko ni da ẹnikẹni lohun tori awọn ko ni ṣe nnkan to le ṣakoba fun akitiyan ijọba to n lọ lọwọ lati doola awọn eeyan ti wọn ji gbe.
Ọmọba Oyelade ni ijọba ko ni fesi si ọrọ MURIC tori ọrọ naa ko le ṣeranwọ lati doola awọn ti wọn ji gbe.
O wa rọ MURIC wi pe ki wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati wa ojutuu si iṣoro eto aabo to n koju ipinlẹ Oyo lọwọ yii.
Kọmiṣọna eto iroyin ni ipinlẹ Oyo sọ pe iroyin ayọ n bọ lori awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe laipẹ.
Ọmọba Oyelade ṣalaye siwaju si i pe ‘’sisọ nnkan ti ijọba n bawọn agbebọn sọ le jẹ ki wọn ṣeku pa wọn.
Bo tilẹ jẹ pe ẹtọ awọn akọroyin ni lati mọ ohun to n lọ ki wọn le sọ fun araalu, amọ, ọrọ to wa nilẹ yii gba ọgbọn ki ọrọ ma baa bẹyin yọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Àwọn agbébọn tó ji wa gbé kò fẹ́ owó tàbí òfin Sharia, ohun tí wọ́n ń fẹ́ rèé... -Olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ Esinele sọ̀rọ̀ nínú fídíò tuntun
Bi ọjọ ṣe n gori ọjọ lori awọn akẹkọọ ati awọn olukọ tawọn ajinigbe ji gbe ni ile ẹkọ ni awọn ilu Esinele ati Yawota ni agbegbe Ogbomoso ni ọsẹ mẹta ni oniruuru iroyin n jade nipa ohun tawọn ajinigbe naa n fẹ lati tu awọn eeyan naa silẹ.
Ni ọsẹ to kọja ni olori ile aṣofin ipinlẹ Oyo, Debo Ogundoyin sọ pe ijọba ko le fun awọn agbebọn naa ni ohun ti wọn n fẹ nitori awọn nnkan naa lagbara pupọ ti ijọba ko si le ṣe wọn.
Lara ohun ti iroyin gbe pe awọn ajinigbe naa n beere fun ni itusilẹ awọn akẹgbe wọn to wa ni ahamọ ijọba, owo biliọnu kan, siṣe amulo ofin Sharia ni ipinlẹ Oyo atawọn nnkan mii.
"Wọn o beere fun owo tabi ofin Sharia, wọn o beere fun nnkan ija ogun, nnkan ẹyọkan ti wọn n beere ni itusilẹ awọn eeyan wọn"
Amọ olukọ agba ile ẹkọ ti wọn ji gbe naa tun ti sọrọ ninu fidio mii tawọn ajinigbe naa gbe sita.
Ninu fidio naa ni Arabinrin Alamu ti rọ awọn akọroyin, atawọn to n gbe iroyin nipa ijinigbe naa lati ṣe pẹlẹ, ki wọn ye gbe ohun ti kii ṣe ootọ.
O ni awọn ajinigbe naa ṣafihan awọn nnkan fun awọn pe awọn eeyan n sọ pe awọn n beere fun ofin Sharia ni ipinlẹ Oyo ati owo lati gba itusilẹ awọn, obinrin naa ni ọrọ ko ri bẹẹ.
O ni niṣe ni awọn eeyan n mu ohun nira sii fawọn nitori awọn ajinigbe naa ni ohun ti awọn n fẹ ko ju lati gba awọn eeyan wọn to wa ni ahamọ silẹ lọ.
Alamu ni "oni lo pe ọjọ mẹrinlelogun ti a ti wa nibi yii, o dabi pe awọn kan n mu ki iṣoro wa peleke sii.
"Wọn fi awọn iwe iroyin kan han wa nibi ti wọn ti kọ sibẹ pe awọn to ji wa gbe n beere fun itusilẹ awọn eeyan kan, wọn beere fun ọkọ, wọn beere fun biliọnu kan naira ati imulo ofin Sharia.
"Awọn nnkan yii kii ṣe ootọ, wọn kan n da iṣoro kalẹ fun wa ni, ko si ẹni to fi tipa mu wa lati maa ṣẹsin Islam, wọn fi wa silẹ laaye wa.
"Wọn o beere fun owo tabi ofin Sharia, wọn o beere fun nnkan ija ogun nnkan ẹyọkan ti wọn n beere ni itusilẹ awọn eeyan wọn.
"A n bẹ awọn eeyan lati ma fi ẹmi wa ṣe oṣelu, a lero pe ijọba maa jiroro pẹlu wọn lati mọ awọn ti wọn fẹ itusilẹ wọn ki awọn naa le gba itusilẹ."
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣẹyin?
Ṣaaju ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti tako aba lati bawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe l'Ogbomoso dunaadura.
Adari ile, Họnarebu Adebo Ogundoyin, lo fi idi ọrọ yii mulẹ lasiko ti ile jiroro lori ọrọ naa.
Ninu fidio kan to ṣafihan ijokoo ile igbimọ aṣofin Oyo ni adari ile ti sọ pe ijọba ko ni sanwo fawọn agbesunmọmi lati fawọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe lominira.
Ogundoyin sọ ninu fidio naa wi pe ''ṣe to ba jẹ pe ẹyin ni gomina ipinlẹ Oyo, ṣe ẹ maa gba lati fun awọn agbesunmọmi ni owo gobọi, nnkan ijagun, ati agbekalẹ ofin ti ko ni tako wọn lọjọ iwaju?
Ṣe ẹyin maa fawọn agbesunmọmi lawọn nnkan yii ti wọn maa fi gbilẹ si i lagbegbe igberiko ti wọn ti n ṣọṣẹ?''
Adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo sọ pe ọpọ eeyan ni ko mọ ẹkunrẹrẹ nnkan tawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe nijọba ibilẹ Oriire n beere fun.
Họnarebu Ogundoyin ṣalaye pe idi niyi tawọn eeyan fi ni lati ṣe suuru lori ọrọ yii.
O ni ijọba yoo fawọn agbesunmọmi ni igboya lati tubọ maa ṣọṣẹ si i ti wọn ba le fun wọn lawọn nnkan ti wọn n beere fun.
Oni ọjọ Ẹti ọjọ karun un oṣu Kẹfa lo pe ọsẹ mẹta ti wọn ti ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn gbe lọ nile ẹkọ ni Esinele ati Yawota l'Ogbomoso.
Ṣaaju ni Aarẹ Bola Tinubu ti bu ẹnu ẹtẹ lu bawọn agbebọn naa ṣe yinbọn pa ọkan lara awọn olukọ ile ẹkọ girama ti wọn ti ji awọn eeyan gbe ni Esinle.
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo naa fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ọhun tun ṣekupa olukọ imọ iṣiro to wa lara awọn ti wọn ji gbe.
Lẹyin naa ni Aarẹ Tinubu paṣẹ fawọn ẹṣọ eleto aabo lati lọ doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa.
Ẹgbẹ awọn olukọ ati oniruuru ẹgbẹ mii lo ti n ṣewọde lati pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ to wa lakata ajinigbe naa.
Amọ, awọn eeyan yii ti wọn le logoji si wa lakata awọn ajinigbe titi di asiko ti a kọ iroyin yii.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awon ajinigbe yabo ile ẹkọ mẹta niluu Ogbomoso.
Ahoro Esinele, Yawota ati Alausa ni wọn ti ṣiṣẹ ibi naa, ti wọn pa olukọ kan lasiko ikọlu, ko akẹkọọ mẹtadinlogoji, olukọ meje wọgbo lọ.
Lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ko wọn lọ ni awọn ajinigbe naa fi aworan ibi ti wọn ti bẹ ori olukọ kan, Micheal Ojedokun, sori ayelujara.
Latigba naa ni igbesẹ ti n waye lati ri awon to wa nigbekun naa gba kalẹ, eyi to ti pe ọsẹ mẹta bayii.























