'Ọ̀pọ̀ ìdẹ́yẹsí làwa tí 'polio' sọ di àkàndá máa ń kojú, àmọ́ àwa náà lè dá sí ìdàgbàsókè ìlú'

Àkọlé fídíò, ‘Ọ̀pọ̀ ìdẹ́yẹsí làwa tí ‘polio’ sọ di àkàndá máa ń kojú, àmọ́ àwa náà lè dá sí ìdàgbàsókè ìlú’
'Ọ̀pọ̀ ìdẹ́yẹsí làwa tí 'polio' sọ di àkàndá máa ń kojú, àmọ́ àwa náà lè dá sí ìdàgbàsókè ìlú'
Published

Àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀, polio, jẹ́ èyí tí kòkòrò àìfojúrí, poliovirus máa ń fà. Ó máa ń tàn látara ìgbẹ́ ẹni tó bá ni tàbí tí itọ́ ẹni tó bá ni bá kan èèyàn llára.

Àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn kò bá ì tíì pé ọdún márùn-ún ló máa ń yọ lẹ́nu.

Àjọ WHO ní èèyàn kan nínú igba ọmọdé tí àìsàn náà bá mú ni ó ṣeéṣe kí ó má lè rìn mọ́ àti ìdá márùn-ún sí mẹ́wàá nínú wọn ló máa ń ṣekúpa nígbà tí wọ́n kò bá ríbi mí mọ́ dáadáa.

Gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára ti mú kí méjì nínú ẹ̀yà kòkòrò náà tó lágbára púpọ̀ di ohun ìgbàgbé àmọ́ ẹyọ̀kan ṣì ń jà.

A ba ọkan lara awọn ti aisan yii n ba finra sọrọ, o si ṣalaye idẹyẹsi ti wọn n koju.