Wo bí ètò ìsínkú gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Temitope Osoba tó jáde láyé láìpẹ́ yìí yóò ṣe lọ

Temitope Osoba fẹyin ninu awọn fọto yii, o lo ẹgba ọwọ ati igo dudu ninu fọto akọkọ, bẹẹ lo lo ẹgba ọrun ati tọwọ ninu fọto keji pẹlu aṣọ alawọ aro to wọ.

Oríṣun àwòrán, Temitope Osoba/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajugbaja oṣerebinrin nni, to fi gbogbo ọjọ aye rẹ ipolongo lori aisan jẹjẹrẹ, paapaa lati fun awọn obinrin to n koju aisan naa ni ireti igbe aye ọlọjọ pipẹ, Temitope Osoba ti jade laye.

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni Temitope Osoba jade laye lẹni ogoji ọdun.

Titi di asiko yii ni awọn oṣere tiata, to fi mọ awọn ololufẹ ere tiata nilẹ Naijiria ati kaakiri agbaye ṣi n kẹdun iku obinrin naa, ti wọn si n sọ pe awọn yoo ṣafẹri rẹ, paapaa lori awọn igbesẹ akikanju to gbe nigba aye rẹ.

Ni bayii, awọn mọlẹbi oloogbe naa ti wa kede ọjọ ti wọn yoo sinku Temitope Kofoworola Osoba ni ilana Kritiẹni.

Ilu Iperu-Remo la gbọ pe wọn yoo sinku gbajumọ oṣere ti irawọ rẹ wọmi lojiji.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn oṣerebinrin nni, Abiola Adekunle ṣe gbe e sori ayelujara rẹ, o ni Ọjọbọ, ọsẹ yii, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni wọn yoo fi eeru fun eeru, ati erupẹ fun erupẹ.

Ninu fọto kan ti oṣerebinrin naa fi soju opo rẹ, o ni agogo mẹsan owurọ ni wọn yoo lọ gbe oku Temitope Osoba kuro ni ile igbokusi ti ile iwosan OSUTH to wa niluu Sagamu, ipinlẹ Ogun.

Lẹyin naa ni wọn yoo ṣẹṣẹ gbe oku rẹ si gbọngan kilọọbu Akesan to wa niwaju ọja aarọ tiluu Iperu, nibi ti wọn yoo ti ṣe isin idagbere fun un.

Gbara ti wọn ba pari eto isin idagbere naa ni wọn yoo too ṣẹṣẹ gbe oku naa lọ si itẹ ti Iperu Remo.

Bi iku Temitope Osoba ṣẹlẹ?

Fọto bi eto isinku Temitope Osoba yoo ṣe lọ

Oríṣun àwòrán, Abiola Adekunle/Facebook

Gbajumọ oṣere ni Oloogbe Temitope Osoba, ọmọ ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun si ni.

O ti kopa ninu ọpọlọpọ iṣẹ ori itage lede Yoruba ati oyinbo, bẹẹ lo si n ṣe pupọ ninu ere igbalode ti a mọ si Skit.

Nnkan bii ọdun meji sẹyin ni Tope Osoba lugbadi aisan jẹjẹrẹ ọmu, nigba to kede pe oun ri apẹẹrẹ koko kekere kan ninu ọmu naa.

Oṣere naa kede pe oun lọ sileewosan, wọn si fidi ẹ mulẹ pe wọn ni lati yọ koko ọyan naa pẹlu iṣẹ abẹ.

O pada bẹbẹ owo lọwọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ṣiṣẹ abẹ naa, wọn si yọ ọ .

Loṣu Keji ọdun 2025 ni BBC News Yoruba ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun Oloogbe Tope Osoba, o si ṣalaye nigba naa pe ko wu oun lati tọrọ owo nita gbangba, amọ nigba ti ko si ọna miran, ti owo naa si gbọdọ pe lo mu oun gbe bẹbẹ iranlọwọ naa.

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 lo ki aye pe o digboṣe.