Èyí lohun táwọn agbébọn ń béèrè lọ́wọ́ ìjọba láti tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti tako aba lati bawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe l'Ogbomoso dunaadura.
Adari ile, Họnarebu Adebo Ogundoyin, lo fi idi ọrọ yii mulẹ lasiko ti ile jiroro lori ọrọ naa.
Ninu fidio kan to ṣafihan ijokoo ile igbimọ aṣofin Oyo ni adari ile ti sọ pe ijọba ko ni sanwo fawọn agbesunmọmi lati fawọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe lominira.
Ogundoyin sọ ninu fidio naa wi pe ''ṣe to ba jẹ pe ẹyin ni gomina ipinlẹ Oyo, ṣe ẹ maa gba lati fun awọn agbesunmọmi ni owo gobọi, nnkan ijagun, ati agbekalẹ ofin ti ko ni tako wọn lọjọ iwaju?
Ṣe ẹyin maa fawọn agbesunmọmi lawọn nnkan yii ti wọn maa fi gbilẹ si i lagbegbe igberiko ti wọn ti n ṣọṣẹ?''
Adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo sọ pe ọpọ eeyan ni ko mọ ẹkunrẹrẹ nnkan tawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe nijọba ibilẹ Oriire n beere fun.
Họnarebu Ogundoyin ṣalaye pe idi niyi tawọn eeyan fi ni lati ṣe suuru lori ọrọ yii.
O ni ijọba yoo fawọn agbesunmọmi ni igboya lati tubọ maa ṣọṣẹ si i ti wọn ba le fun wọn lawọn nnkan ti wọn n beere fun.
Oni ọjọ Ẹti ọjọ karun un oṣu Kẹfa lo pe ọsẹ mẹta ti wọn ti ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn gbe lọ nile ẹkọ ni Esinele ati Yawota l'Ogbomoso.
Ṣaaju ni Aarẹ Bola Tinubu ti bu ẹnu ẹtẹ lu bawọn agbebọn naa ṣe yinbọn pa ọkan lara awọn olukọ ile ẹkọ girama ti wọn ti ji awọn eeyan gbe ni Esinle.
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo naa fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ọhun tun ṣekupa olukọ imọ iṣiro to wa lara awọn ti wọn ji gbe.
Lẹyin naa ni Aarẹ Tinubu paṣẹ fawọn ẹṣọ eleto aabo lati lọ doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa.
Ẹgbẹ awọn olukọ ati oniruuru ẹgbẹ mii lo ti n ṣewọde lati pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ to wa lakata ajinigbe naa.
Amọ, awọn eeyan yii ti wọn le logoji si wa lakata awọn ajinigbe titi di asiko ti a kọ iroyin yii.
Ṣé lóòótọ́ làwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso ti gbòmìnira? Ìjọba Oyo sọ̀rọ̀

Ijọba ipinlẹ Oyo ti ṣalaye pe irọ to jina si ootọ ni fidio tawọn eeyan kan n pin kaakiri ori ayelujara wi pe awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso ti gba ominira.
Kọmiṣọna eto iroyin ati ọgbọn inu ni ipinlẹ Oyo sọ pe ijọba Gomina Seyi Makinde si n tẹsiwaju akitiyan rẹ lati ri pe awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa kuro lakata awọn ajinigbe.
Ọgbẹni Oyelade ni igbiyanju ijọba n tẹsiwaju lati ri pe awọn ti wọn ji gbe ni Esinele ati Yawota ni ijọba ibilẹ Oriire pada wale ni alaafia laipẹ.
Ọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un to kọja ni awọn janduku agbebọn yabo ilu Esinele ati Yawota nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ ati olukọ to le ni ogoji lọ.
Fayose nílò àdúrà, ẹ ṣàánú rẹ̀ – Makinde da padà lẹ́yìn tí Fayose ní ó lè jẹ́ òun ló ṣagbátẹrù ìjínigbé Ogbomoso

Ijọba ipinlẹ Oyo ti rọ awọn araalu ki wọn dide adura fun gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayodele Fayose, lẹyin to ni o fi ẹsun ti kii ṣe ootọ kan oun.
Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun iroyin ipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade fi lede lorukọ gomina Seyi Makinde, o ni iyalẹnu nla ni ẹsun ti Fayose fi kan Makinde jẹ.
Ṣaaju ni Fayose ti kọkọ sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ijọba ipinlẹ naa lo wa nidi ijinigbe to waye ni ijọba ibilẹ Oriire lati mọọmọ tabuku ijọba Aarẹ Bola Tinubu.
Ijọba ipinlẹ ti wa sọ pe irọ ni ẹsun naa, ati pe o jẹ eyii to wuwo ti ko si tọ ko maa ti ẹnu eekan ilu bii ti Fayose jade.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ohun to kan Makinde bayii ni bi yoo ṣe doola awọn ọmọde ati olukọ to wa lakata ajininigbe, kii ṣe lati ma gba ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ bii ẹni gba igba ọti.
O ni kii ṣe igba akọkọ ree ti Fayose yoo sọrọ kobakungbe nipa Makinde.
Oyelade mẹnuba asiko ti Fayose sọ ninu iṣu Kẹrin ọdun yii pe Makinde n gbimọ lati yọ Olubadan ilu Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja loye, eyii ti ko ri bẹẹ.
Lẹyin naa lo ni ki awọn araalu ma ka ọrọ Fayose kun amọ ki wọn sọ ireti nu nitori pe Makinde n ṣiṣẹ lọsan ati loru lati doola awọn olukọ ati akẹkọọ naa ti wọn wa lakata ajinigbe.
Ó lè jẹ́ ìjọba Makinde ló ṣagbátẹrù ìjínigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ l'Ogbomoso láti ba orúkọ Tinubu jẹ́ - Fayose

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayo Fayose, ti sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ wi pe ijọba ipinlẹ Oyo lo ṣagbatẹru ijinigbe awọn akẹkọọ ati olukọ to ṣẹlẹ l'Ogbomoso.
Fayose to sọrọ yii ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe lori ileeṣẹ tẹlifisan Channels lalẹ ana ọjọ Aje sọ pe ijọba Gomina Seyi Makinde le ṣe eleyii lati ba orukọ Aarẹ Bola Tinubu jẹ.
Iṣẹlẹ ijinigbe naa ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ kaakiri ori itakun ayelujara.
Lopin ọsẹ to kọja ni Aarẹ Tinubu ran igbimọ ẹlẹni marun un lọ si Ahoro Esinele ati Yawote l'Ogbomoso nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.
Igbimọ naa si ṣeleri wi pe awọn ẹṣọ eleto aabo yoo ri pe awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe pada sile ni alaafia.
Amọ, Fayose ti sọ pe ojuṣe ijọba ipinlẹ ni lati ri pe eto aabo to peye wa fun araalu ki ọrọ to kan ijọba apapọ.
Fayose ni idi niyii tawọn gomina fi n gba owo gobọi loṣooṣu fun eto aabo.
''Ki ọrọ to o kan ijọba apapọ, ijọba ibilẹ ati ijọba ipinlẹ wa nibẹ.
Gomina Makinde ko ṣiṣẹ rẹ bii iṣẹ lori ọrọ ijinigbe to ṣẹlẹ l'Ogbomoso, oṣelu ni gomina gbaju mọ dipo ọrọ eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ rẹ.
Lẹyin ti wọn ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa gbe tan ni Makinde kopa ninu ibo abẹnu sipo aarẹ.
Ko gbe igbesẹ kankan lori ijinigbe to ṣẹlẹ, lẹyin to wọle ibo abẹnu tan ni o to lọ ṣabẹwo si ẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe,'' Fayose lo sọ bẹẹ.
Gomina ipinlẹ Ekiti sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ijọba ipinlẹ Oyo lo wa nidii iṣẹlẹ ọhun lati le jẹ kawọn araalu maa sọrọ ti o dara nipa ijọba Tinubu.
Ọpọ eeyan lo ti bẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ ijinigbe naa, wọn si ti kepe ijọba apapọ lati doola awọn to wa lakata ajinigbe naa.
BBC Yoruba kan si ijọba ipinlẹ Oyo lati fesi sọrọ ti Fayose sọ, amọ, wọn o fesi kankan titi to fi di asiko ti a kọ iroyin yii.


























