Níbí ni a ó fi àdàgbá ìròyìn gbogbo bó ṣe ń lọ ní ìpínlẹ Ọṣun rọ̀ sí láti ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC Yoruba tó ń wá láti ọwọ́ Olubusola Afolayan àti Yetunde Olugbenga.
A ó máa mú bó ṣe tún ń tẹ̀ síwájù wá sí etí ìgbọ́ yín lórí ìkanni yìí, bbc.com/yoruba.
Loni ọjọ kejìlélógún, oṣù kẹsan an, ọdún 2018 ni àwọn èèyàn ìpínlẹ Ọṣun yóò dìbò yan ẹni tó wù wọ́n sìpó gomina fún ọdún mẹrin tó m bọ.
Olubusola Afolayan and Yetunde Olugbenga
Níbí ni a ó fi àdàgbá ìròyìn gbogbo bó ṣe ń lọ ní ìpínlẹ Ọṣun rọ̀ sí láti ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC Yoruba tó ń wá láti ọwọ́ Olubusola Afolayan àti Yetunde Olugbenga.
A ó máa mú bó ṣe tún ń tẹ̀ síwájù wá sí etí ìgbọ́ yín lórí ìkanni yìí, bbc.com/yoruba.
5:37 Idibo ti pari ni ibudo ti Họnọrebu Lasun Yusuf ti tẹka. Awọn oṣiṣẹ ajọ INEC ti n wogile awọn iwe idibo to ṣẹku ni igbaradi fun kika ibo.
Àkọ̀ròyin BBC tó wà ní wọ́ọ̀dù yìí jábọ̀ wí pé ẹ̀rọ tó ń ṣe àyẹ̀wò káàdì ìdìbò tí wọ́n ń lò yọnu nítorí ṣe ni bátììrì rẹ̀ń kú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Èyí fa ìfàsẹ́yìn títí tí alábojútó wá ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wọn.
Lọ̀gán tí wọ́n párí ìdìbò náà ni kíkà yóò bẹ̀rẹ̀.

Olùdíjé sípò Gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Gboyega Oyetola ló m'ókè ni ibùdó ìdìbò rẹ to wá ní Iragbiji, wọ́ọ̀dù kínní ẹ̀ka kejì.
PDP - 134
APC - 351
SDP - 6
ADP - 25
ADC - 2

Oríṣun àwòrán, @Gboyega Oyetola
4:57 Awọn oludibo bii mọkanlelogun ṣi wa lori ila ni ward 5, unit 4, ijọba ibilẹ Irepọdun ilu Ilobu, nibi ti Họnọrebu Lasun Yusuf ti dibo.
Olùdíjé sípò Gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADP Moshood Adeoti ló jáwé olú borí ni ibùdó ìdìbò rẹ to wá ní Post Office, wọ́ọ̀dù kejìlá ẹ̀ka 4 ní ìlú Iwo.
SDP - 17
APC - 24
PDP- 17
ADC- 4
ADP- 153

Oríṣun àwòrán, @Moshood Adeoti
Arẹgbẹṣola jáwé olubori nibudo ìdìbò rẹ̀ ni Ifọfin ni ẹka kinni ni wọọdu kẹjọ ni Ileṣa
APC 71
PDP 54
ADC 2
ADP 27
SDP 12

Ajọ eleto idibo ṣe ikilọ pe ki àwọn eniyan ṣọra fún kikede èsì idibo ti kò tọ̀nà lori ikanni twitter wọn
Esi idibo wọọdu Adeleke ti jade o.
PDP 154
APC 35.
SDP 0
ADP 0
ADC 0
E wo bi idunnu ṣe ṣubu layọ
Wọn ti n ka ìbò ibudo ti Arẹgbẹṣola ti dibo ni Ileṣa
Awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ni Ile-Ifẹ ṣalaye iwoye wọn lori idibo oni
Awọn èniyan ilu Iwo ṣi n dibo lọ nibudo idibo wọọdu kejila ni Gidigbo nibi ti Moshood Adeoti to n dije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADP ti dibo tẹlẹ




Àwọn oludibo ti n duro dé ìbò kíkà ni Ifọn




Àgùnbánirọ̀ tó wà ni ọ̀kan lára ibùdó ìdìbò bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀rọ ayẹkáàdìwò tí wọn n lò.
O ni ẹrọ káàdì náà ń mú iṣẹ́ falẹ̀.
Eyi ṣẹlẹ ni ìdí ayan àti Ìróyè ni iwọ oorun Ileṣa.
INEC n ba àwọn ènìyàn Ariwa Ẹdẹ sọrọ ṣaaju kíka ìbò wọn nijọba ibilẹ Adeleke Ademola ti PDP.

Kọmiṣona fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọsun ṣalaye pe ètò ìdìbò naa lọ daadaa.
Ibudo ajọ INEC ni Oṣogbo ni won yoo ti kede gomina tuntun fún Ọṣun bi èsì ba ṣe n jade

Ibudo idibo Boluwaduro ni wọọdu kẹrin ni Oṣogbo ti pari idibo, won si n duro ki aago meji lù ki wọn bẹrẹ kika ibo ni.
Ọga ọlọpaa Nàìjíríà, Ibrahim Idris, fi agbófinró 18, 426 ránṣẹ́ láti ṣiṣẹ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò míràn.
Ibùdó ìdìbò 3, 010 ni ó wà nipinlẹ Ọṣun tí ìdìbò ti n waye loni.
Ọga ọọ́pàá ni, ó kéré tán, agbofinro mẹrin ló máa wà ní ibùdó ìdìbò kọọkan.


Lasun Yusuf ni ki awọn eniyan dìbò bi o ti yẹ
Ogbaagba ni yii ti Oludije ADC ti dibo loni



Awọn abilekọ ilu Ifọn pọn ọmọ lọ sibudo idibo láti yan ẹni ti ọkan wọn fẹ
