Àdó olóró àwọn ajínigbé pa Shuaibu aṣọ́gbóọba lásìkò tó ń lé àwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé ní Oriire, àwọn ẹbí rẹ̀ pariwo síta
Oṣiṣẹ aṣọgbo ni Shuabu Adigun, ọkan lara awọn eeyan to kọkọ le awọn ajinigbe to ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe ni Oriire ni ipinlẹ Ọyọ ni ọjọ karundinlogun oṣu karun un ki o to kagbako iku ojiji.
Ẹbi oloogbe naa ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ilu Ọyọ ni oloogbe naa ti n ṣiṣẹ, amọṣa o gba isinmi ni ibi iṣẹ rẹ lo fi wa wo awọn ẹbi rẹ nilu wọn ni ilu Yawọta ni ijọba Oriire nigba ti iṣẹlẹ naa waye.
Shuaibu atawọn eeyan kan lo kọkọ gbiyanju lati le awọn ajinigbe naa ki wọn si gba awọn ti wọn ko pada. Ori ọkada rẹ lo wa to si n le awọn agbebọn naa, ọkada naa gun ori ado afọkuta kan ti awọn eeyan naa gbin silẹ lo fi dero ọrun.
- Ẹkún sọ níbí ìsìn ìrántí fún olóògbé John Olaleye olùkọ́ Oriire táwọn jàndùkú ajínigbé ṣekúpa
- ''Ohun tó kàn fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Oríire tó bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé rèé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ọ́...''
- Gbogbo ìgbà ti ọmọ mi bá rí àlejò ni ẹ̀rù máa ń bà á báyìí – Ìyá akẹ́kọ̀ọ́ tó gba ìtúsílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Iléẹṣẹ́ ológun Nàìjíríà ṣàlàyé iṣẹ́ oṣù kan tí wọ́n fi gba akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ Oríire lọ́wọ́ ajínigbé
Awọn idile rẹ ṣalaye fun BBC pe iyawo mẹta ati ọmọ mẹwaa ni arakunrin naa fi silẹ ki ọlọjọ to de.
Haminat Adigun to jẹ ọkan lara awọn iyawo oloogbe naa ṣalaye pe Oloogbe naa pe oun pe oun gba isinmi lẹnu iṣẹ amọ "oun fẹ lo anfani naa lati lọ wo awọn ẹbi oun ni ilu Yawọta ati pe oun yoo lo ọjọ meji".





