DSS fi ojú afurasí márùn-ún ba ilé-ẹjọ́ lórí ìjínigbé tó wáyé l'Oyo

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga
L'Ọjọru, ọsẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ẹka ti DSS fi oju afurai marun-un tọwọ tẹ lori ikọlu ijinigbe ti awọn akẹkọọ ati olukọ to waye nipinlẹ Oyo.
Mahmud Muhammad, ti wọn tun n pe ni Abu Bara'a ati Abbas Mukhtar; Abubakar Abbas, ti wọn tun n pe ni Isah Adam ati Mallam Mahmuda Al-Nigeri; Abdulrazak Umar, ti wọn tun n pe ni Abu Khalifa/Abu Khalid; Yunusa Musa, ti wọn tun n pe ni Abu Yunusa Bin Musa; ati Shamsu Adamu Sani, toun naa tun n jẹ Abu Itisar ni DSS foju wọn han niwaju ile-ẹjọ giga tiluu Abuja.
Awọn maraarun yii ni DSS sọ pe awọn fura si wi pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Jama'atu Ansarul Muslimina fi-Biladis Sudan, ti ọpọ mọ si Ansaru, ti wọn si ṣe ikọlu si awọn olukọ ati akẹkọọ nijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo lọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un.
Lasiko ijinigbe ọhun la gbọ pe wọn pa awọn olukọ meji danu, ti wọn si fi wọn pa oroko ranṣẹ si ijọba ipinlẹ Oyo.
Awọn mẹfẹẹfa la gbọ pe wọn sọ niwaju ile-ẹjọ wi pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun to nii ṣe pẹlu gbigbe ibọn, igbimọ papọ, gbigbe-sunmọmi, to fi mọ ṣiṣe agbatẹru iwa igbesunmọmi ati gbigba awọn iroyin.
Ẹsun naa ni nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CR/438/2026, ni ijọba apapọ ti fẹsun kan wọn wi pe Muhammad ati Abbas paṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ti Ansaru lati ji awọn eeyan gbe, ki wọn si maa pa wọn kaakiri Naijiria bi wọn ba rọwo to wọn, pẹlu erongba lati jẹ ki ijọba ṣe ohun ti wọn ba n fẹ.
Lara ohun ti wọn sinu iwe ẹsun naa ka pe, "Wipe iwọ… lawọn asiko kan laaarin ọdun 2025 ati 2026, layika ile ẹjọ yii, paṣẹ fun awọn ologun abẹ rẹ ti ẹgbẹ agbesunmọmi Jama'atu Ansarul Muslimina fi-Biladis Sudan (ANSARU)... wi pe bi ijọba ba rọwọ to yin, ki ẹyin naa pa, ki ẹ si ji awọn eeyan gbe, lati le jẹ ki ijọba ṣe awọn ohun ti ẹ ba n fẹ...ati pe fun idi ẹyi,ẹ ti tapa si abala kẹrinlelogun ninu iwe ofin gbigbe sunmọmi lorileede yii ti ọdun 2022, to si niijiya ni ipin keji, isọri keji ni abala kẹrinlelogun kan naa."
Ajọ DSS tun sọ ninu iwe ẹsun naa pe awọn afurasi wọnyi ṣeku pa eeyan meji, Michae Oyedoku ati John Olaleye nipa gige wọn lori.
Siwaju sii ni ajọ DSS wa tun fẹsun kan awọn marun-un naa pe wọn gbọ nipa iroyin ati itọni naa, wọn ko si fi to awọn ileeṣẹ eleto aabo leti, nigba ti wọn tun fẹsun miran kan Umar, Musa ati Sani, leyi to nii ṣe pẹlu ṣiṣagbatẹru ijinigbe ati ipaniyan.
Pẹlu gbogbo ẹbẹ wọn, agbefọba, Ọmọwe Caliatus Eze, rọ ile-ẹjọ lati jẹ ki awọn afurais naa wa ni ahamọ DSS titi digba ti igbẹjọ yoo tun fi waye, ti Onidajọ Salim Ibrahim si gba sii lẹnu.
Adajọ naa fi kun ọrọ rẹ wọn ko gbọdọ di awọn agbẹjọro awọn afurasi naa lọwọ lati ri wọn nigbakugba, to fi mọ meji ninu awọn mọlẹbi wọn, bẹẹ si ni wọn gbọdọ lanfaani ni eto aabo to pe ye.
O wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan, ọdun 2026.


























